Jọkẹ Amọri
Ile-ẹjọ kan to fikalẹ si olu ilu ilẹ wa, niluu Abuja, ti fọwọ osi da ẹjọ tawọn kan pe pe ki wọn ma gbọ ẹsun ayederu iwe-ẹri ti wọn fi kan oludije sipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu APC, Aṣiwaju Bọla Tinubu.
Lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni kootu dajọ pe ẹjọ ti awọn ẹka kan ninu ẹgbẹ AA, iyẹn Action Alliance, pe pe kile-ẹjọ ma gbọ ẹjọ ẹsun ayederu iwe-ẹri ti wọn fi kan Tinubu ko lẹsẹ nilẹ.
Awọn kan ti wọn jẹ alatilẹyin fun Tinubu ninu ẹgbẹ naa ni wọn ni ki wọn so awọn pọ mọ ẹjọ ayederu iwe-ẹri ti awọn ọmọ ẹgbẹ naa kan pe Tinubu. Awọn eeyan naa, eyi ti Adekunle Ọmọ-Aje ko sodi ni wọn lọ si kootu, ti wọn si bẹ ile-ẹjọ pe ko so awọn pọ mọ ẹjọ ọhun. Ṣugbọn kootu sọ pe awọn idi ti wọn fi sọ pe ki kootu so awọn mọ ẹjọ naa ko le mu ipalara ba ẹjọ yii ti wọn ko ba so wọn pọ mọ ọn. Wọn ni ọkunrin naa ko fi ẹri to to kalẹ lati fi han pe ohun ni alaga apapọ ẹgbẹ ọhun gẹgẹ bo ṣe sọ.
Onidaajọ Obiora Egwuatu sọ pe bii alayọjura ati alayọnuso to n da si ohun ti ko kan wọn ni wọn maa jẹ lati sọ pe ki wọn so awọn pọ mọ ẹjọ ọhun.
Awọn eeyan ti wọn jẹ alatilẹyin Tinubu ninu ẹgbẹ Action Alliance, ni wọn gba ile-ẹjọ lọ pe ki kootu ma gbọ ẹjọ ayederu iwe-ẹri ti awọn kan ninu ẹgbẹ wọn pe oludije funpo aarẹ lẹgbẹ oṣelu APC yii.
Ni bayii ti adajọ ti da ẹjọ naa nu, ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrin, oṣu Kọkanla, ọdun yii, ni igbẹjọ yoo bẹrẹ ni pẹrẹu lori ẹjọ naa. Adajọ si ti paṣẹ pe ki awọn olupẹjọ tete pese ẹlẹrii wọn silẹ ki igbẹjọ naa le tete pari ni asiko to yẹ labẹ ofin.
Tẹ o ba gbagbe, ẹgbẹ Action Alliance yii lo gbe Tinubu lọ si kootu, ninu oṣu Kẹfa, ọdun yii, ti wọn si ni ki ajọ eleto idibo ilẹ wa ma fi orukọ rẹ sinu awọn ti yoo dije dupo aarẹ nitori pe ayederu iwe-ẹri lo n ko kiri.
Ninu iwe ipẹjọ naa ni wọn ti sọ pe ẹgbẹ APC ati Tinubu ko lẹtọọ lati kopa ninu ibo aarẹ ọdun 2023 nitori ayederu iwe-ẹri to ko kalẹ lọdun 1999.