Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Ọkunrin ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn kan, Eric Ayọkunle, ni ile-ẹjọ giga ti ipinlẹ Ekiti ti paṣẹ pe ko maa lọ sẹwọn gbere lori ẹsun pe o fipa ba ọmọdebinrin ẹni ọdun mẹtadinlogun kan lo pọ.
Gẹgẹ bi iwe ẹsun ti wọn fi kan Ayọkunle ṣe sọ, wọn ni ninu igbo kan to wa laarin Ilawe-Ekiti si Igbara-Odo ni ọdaran naa to jẹ ọlọkada ti fipa ba ọmọdebinrin ẹni ọdun mẹtadinlogun kan lo pọ lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kejila, ọdun 2019.
Ẹsun yii ni ile-ẹjọ sọ pe o lodi sofin ifipa ba obinrin lo pọ ati ofin titẹ ẹtọ ọmọbinrin mọlẹ to jẹ ofin keje ipinlẹ Ekiti ti ọdun 2012.
Ninu awijare rẹ ni teṣan ọlọpaa, ọmọdebinrin yii ni ọjọ ti iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ, oun fẹẹ lọ lati Igbara-Odo si Ilawẹ-Ekiti lati lọọ gbe ounjẹ fun iya oun ati iyawo ẹgbọn oun to ṣẹṣẹ bimọ tuntun sileewosan ijọba ni Ilawẹ-Ekiti ni lọjọ ọdun Keresimesi. O ṣalaye pe Ayọkunle to jẹ gbajugbaja ọlọkada ni Igbara-Odo loun pe ko gbe oun lọ si Ilawẹ-Ekiti, to si sọ fun pe oun yoo gba aadọrin Naira (500).
O ni bo ṣe gbe oun de Ilawẹ-Ekiti lo duro lati gbe oun pada si Igbara-Odo.
Ọmọbinrin yii ni bi awọn ṣe n pada bọ ni Ayọkunle dari ọkada rẹ wọ inu igbo lọ, nigba ti oun si beere lọwọ rẹ pe nibo lawọn n lọ pe o sọ foun pe oun fẹẹ gba ọna miiran ki awọn ọlọpaa too wa loju ọna ma ri oun.
Ọmọdebinrin yii sọ pe ni kete ti ọlọkada yii rin diẹ ninu igbo, oun kigbe, ṣugbọn oun ko ri ẹnikan kan lati gba oun, o ṣalaye pe ọlọkada yii lo fipa ba oun lo pọ, bo tilẹ jẹ oun n ṣe nnkan oṣun lọwọ.
O ṣalaye pe ni kete ti oun jade kuro ninu igbo naa ni oun lọọ fi ọrọ naa to ọlọpaa to wa loju ọna leti, ti wọn si mu un lẹyin iṣẹju diẹ ti oun fi ọrọ naa to wọn leti, ti wọn si mu un ni kete to kọja si ọdọ awọn ọlọpaa naa.
Nigba to n fi idi ẹjọ rẹ mulẹ lasiko igbẹjọ naa, Agbefọba, Ọgbẹni Kunle Adeyẹmọ, pe ẹlẹrii mẹta, eyi ti Dokita to ṣe ayẹwo fun ọmọdebinrin naa wa lara wọn ati ọlọpaa to n ṣe iwadii ọrọ naa. Bakan naa lo tun mu esi abajade ayẹwo to ṣe fun ọmọ naa wa sile-ẹjọ yii.
Ṣugbọn niṣe ni ọdaran naa sọrọ lorukọ ara rẹ, ti ko si pe ẹlẹrii kankan.
Onidaajọ Adekunle Adelẹyẹ sọ pe ọdaran naa kuna lati mu ẹri pe ọmọdebinrin naa jẹ ololufẹ oun ki iṣẹlẹ ifipa ba ni lo pọ naa too ṣẹlẹ.
Bakan naa ni adajọ naa tun ṣalaye pe agbefọba naa ti fi idi ẹsun ifipa ba ni lo pọ mulẹ ṣinṣin pẹlu awọn ẹri to ko wa si ile-ẹjọ naa.
Oni ọdaran naa jẹbi ẹsun ifipa ba ni lo pọ, ile-ẹjọ naa si paṣẹ pe ko maa lọ si ẹwọn gbere, gẹgẹ bi ofin fifi iya jẹ ọmọbinrin ati fifipa ba obinrin lo pọ ṣe la a silẹ ninu iwe ofin ipinlẹ Ekiti ti wọn kọ ni ọdun 2012.