Faith Adebọla
Ọkunrin ẹni ọdun mẹtalelogun kan, Blessing Okon, ko ro o rara, tori idajọ to gba lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu ki-in-ni yii, ko mu ibukun kan dani fun un, ẹwọn gbere nile-ẹjọ ju u si latari bi wọn ṣe fidi ẹ mulẹ pe o jẹbi ifipabanilopọ nileewe to ti n ṣiṣẹ ọdẹ. Ọmọọdun mẹrinla lo fipa ṣe ‘kinni’ fun.
Ijọba ipinlẹ Eko lo wọ olujẹjọ yii lọ sile-ẹjọ lori ẹsun pe o fi ibalopọ halẹ mọ akẹkọọ ileewe, o si tun ba ọmọbinrin ti wọn forukọ bo laṣiiri naa tage lai yẹ.
Alaye tawọn lọọya mejeeji to ṣoju fun ijọba, Ọgbẹni Oluṣọla Ṣonẹyẹ ati Abilekọ Olufunkẹ Adegoke, ṣe ni kootu kidaajọ too waye ni pe ni ọjọ kẹtala, oṣu kẹsan-an, ọdun 2019, ni ọdaran yii huwa palapala ọhun nile kan to wa l’Opopona Ribadu, nitosi ọna Awolọwọ, lagbegbe Ikoyi, l’Erekuṣu Eko, lọhun-un, ko si ti i ju ọmọ ogun ọdun nigba yẹn.
Ẹlẹrii mẹta lo jẹrii tako o lasiko igbẹjọ, ọkọọkan wọn lo si fidi ẹ mulẹ pe loootọ ni Blessing huwa ainitiju ọhun, lara awọn ẹlẹrii naa ni baba ọmọbinrin naa, dokita to ṣayẹwo iṣegun, ati ọmọbinrin naa funra rẹ.
Wọn lọmọbinrin naa jẹwọ pe latigba toun ti wa lọmọ ọdun mẹsan-an ni ọdaran yii ti maa n ba oun ṣerekere, bii ko maa tẹ oun lọmu, ko maa gbe ọyan oun sẹnu, tabi ko maa fọwọ pa oun lawọn ibi kọlọfin ara.
Lọjọ iṣẹlẹ ọhun, ojiṣẹ Ọlọrun kan to n gbe inu ọgba ileewe naa lawo iṣẹlẹ naa ya si lọwọ, to si fi to baba ọmọ ọhun leti, kọrọ too di ti ọlọpaa. Adajọ si gboṣuba fun ojiṣẹ Ọlọrun naa pe ko daṣọ bo iwakiwa bii eyi lori mọlẹ.
Bo tilẹ jẹ pe Blessing jiyan pe ko ri bẹẹ, irọ ni wọn n pa mọ oun, Adajọ kootu to n gbọ awọn ẹsun akanṣe ati iwa ọdaran abẹle, Abiọla Sọladoye, sọ lasiko to n gbe idajọ rẹ kalẹ pe olupẹjọ pese ẹri to pọ to lati fidi iwa ọdaran yii mulẹ, pe loootọ lafurasi naa jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.
Adajọ naa ni: “Olujẹjọ yii o tiẹ lẹmii ironupiwada kan bo ti wu ko mọ, pẹlu bi ẹri ṣe fihan pe o ba ọmọ ọdun mẹrinla ṣeṣekuṣe. Ko si iyemeji ninu awọn ẹri to wa niwaju ile-ẹjọ yii, tori bẹẹ, o gbọdọ jiya ẹṣẹ ibalopọ odi rẹ ni.
“Mo paṣẹ ki wọn sọ olujẹjọ yii sẹwọn gbere, ko si sanfaani sisanwo itanran fun un.
“Ki wọn kede orukọ ẹ ninu iwe awọn afipabanilopọ to wa lọwọ ijọba ipinlẹ Eko.”
Bẹẹ ni adajọ kede, ti Blessing Okon si ti kekere wẹwọn.