Adajọ ju ọga onimọto to fipa ba ọmọ ọdun mẹrindinlogun lo pọ sẹwọn gbere

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ile-ẹjọ giga kan to fikalẹ sipinlẹ Ekiti, ti paṣẹ pe ki ọkunrin ẹni ọdun mejilelogoji (42) kan, Ọgbẹni Adewale Ilesanmi, maa lọ si ẹwọn gbere lori ẹsun pe o fipa ba ọmọdekunrin ẹni ọdun mẹrindinlogun kan lo pọ ni Iṣan-Ekiti, nijọba ibilẹ Ọyẹ, ipinlẹ Ekiti.

Ilesanmi to jẹ ọga agba ninu igun ẹgbẹ onimoto kan ni Isan-Ekiti, ijọba ibilẹ Ọyẹ, ni wọn gbe wa si iwaju Onidaajọ Monisọla Abọdunde, lọjọ kẹrindinlogun oṣu Kejila, ọdun 2021.

Gẹgẹ bi iwe ẹsun ti wọn fi kan an ṣe sọ, ọjọ kẹtala, oṣu Keji, ọdun 2021, lo ṣẹ ẹṣẹ naa ni Iṣan-Ekiti. Iwa to hu yii ni wọn ni o lodi sofin, to si ni ijiya Gẹgẹ bi awọn ọlọpaa ṣe sọ, Ilesanmi nio  fipa ba omodebinrin ẹni ọdun mẹrindilogun kan lopọ, ẹsẹ yii ni wọn sọ pe o lodi sofin ifipabanilopọ ti ipinlẹ Ekiti, ti wọn kọ lọdun 2012.

Ọmọdebinrin ti Ilesanmi fipa ba lo pọ yii ṣalaye pe lọjọ ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ, baba oun lo ran oun niṣẹ lati Iṣan-Ekiti lọ si Iludun-Ekiti, lati lọọ gba owo wa, to si fun oun ni kaadi pelebe ti wọn fi n gba owo jade lati ẹnu ẹrọ.

O ni nigba ti oun n pada bọ loun juwọ si mọto ọdaran naa pe ko gbe oun de Iṣan-Ekiti, ṣugbọn ni kete ti oun wọ inu ọkọ naa ti awọn rin siwaju diẹ ni Ilesanmi fi ọwọ kan ọmu oun, ti oun si sọ fun unpe ko fi oun silẹ.

O ni bawọn ṣe de oriko kan, nibi ti igbo kekere kan wa, loju ọna naa lo ṣadeede da ọkọ naa duro, eleyii to fa a ti oun fi ṣilẹkun ọkọ naa, ti oun si bẹrẹ si sa wọ inu igbo lọ.

O ṣalaye pe lọgan lọkunrin naa bọ silẹ, to si bẹrẹ si i le oun, nigba to ba oun lo di oun lọwọ mu pe ti oun ko ba gba ki oun ba oun lo pọ, ada ti oun fi sinu ọkọ loun yoo fi ge ori oun sinu igbo naa, o fi kun un pe lọgan lo bọ gbogbo aṣọ oun, to si fipa ba oun lo pọ.

O fi kun un pe oun ja gbogbo aṣọ okunrin yii boya o le fi oun silẹ, ti oun tun di ẹyin mọ ọn lapa, ṣugbọn ko fi oun silẹ, o ni lẹyin to fipa ba oun lo pọ tan lo ko owo ati kaadi ti baba oun fi ran oun niṣẹ pada fun oun, to si bẹrẹ si i bẹ oun pe ki oun ma ṣe sọ fun ẹnikẹni.

Ọmọbinrin yii ni nigba ti oun pada jade si oju ọna, oun ri baba oun lori ọkada, nibi to ti n wa oun kiri, o ni lọgan loun fi gbogbo ohun to ṣẹlẹ to baba oun leti. Ẹyin eyi lo ni baba oun fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa leti, ti wọn fi mu ọkunrin onimoto yii.

Lati fi idi ẹri ọrọ rẹ mulẹ, Pọsikutọ ile-ẹjọ naa, Arabinrin Folasade Alli, pe ẹlẹrii mẹta, bakan naa lo mu pata, ada nla kan ati iwe esi ayẹwo ti awọn  dokita ṣe fun ọmọdebinrin naa,  o tun mu iwe ti awọn ọlọpaa fi gba ohun silẹ lẹnu ọmọdebinrin naa silẹ gẹgẹ bii ẹri.

Ṣugbọn ni ti ọdaran naa, Agbẹjọro rẹ, Ọgbẹni Tajudeen Omidoyin, lo sọrọ lorukọ rẹ, ko si pe ẹlẹrii kankan.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Onidaajọ Monisọla Abọdunde, kọminu si bi ẹsun ifipabanilopọ, ni pataki ju lọ, fifipa pa ba majeṣin lo pọ ṣe wọpọ lakooko yii ni agbegbe ile-ẹjọ naa.

O ṣalaye pe bi eeyan ba ti jẹbi ẹsun ifipabanilopọ, ipo to wu ki iru ẹni bẹẹ di mu lawujọ, o ni lati lọọ fi oju wina ofin.

Adajọ Abọdunde fi kun un pe yatọ si eyi, nipa bibọwọ fun ofin, oun ko ni ohun miran lati ṣe nipa ẹjọ naa pẹlu gbogbo ẹri to ti wa niwaju kootu ju pe ki ile-ẹjọ sọ ọdaran naa si ẹwọn gbere pẹlu iṣẹ aṣekara.

 

Leave a Reply