Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Lasiko tawọn eeyan n ṣe iṣọ-oru lọwọ ni ṣọọṣi Sẹlẹ kan, Itunu Parish, to wa lagbegbe Ilawo, l’Abẹokuta, ni ọmọkunrin kan, Samuel Afọlabi, ẹni ọdun mọkanlelogun, fo ferese wọle, to si ji foonu Techno Camon 16 ati ẹgbẹrun mejilelọgọta naira (52,000), iyẹn lọjọ kẹrinlelogun, oṣu keji, ọdun 2021.
Ọwọ palaba rẹ pada segi nipasẹ irinṣẹ igbalode kan ti wọn fi maa n wadii ibi ti foonu ba wọlẹ si, ọlọpaa si mu un. Ọrọ pada de kootu, Samuel jẹwọ pe loootọ loun wọ ṣọọṣi jale.
Kootu Majisreeti l’Abẹokuta ni wọn ti gbọ ẹjọ naa lọsẹ to kọja yii, Adajọ D.S Ogongo si paṣẹ pe ki ọmọkunrin naa lọọ ṣẹwọn ọdun kan lai si aaye owo itanran rara.
Ṣaaju ni agbefọba Ọlaide Rawlings, ti ṣalaye fun kootu pe ẹgbẹrun mẹrindinlọgọrin naira (76,000) ni wọn n ta foonu ti Samuel ji. Ganiu Adeọla lo ni foonu naa gẹgẹ bo ṣe wi. Bakan naa lo ni o tun ji ẹgbẹrun mejilelaaadọta naira ti i ṣe ti Ọgbẹni Dare Theophilus.
O ni gbogbo ẹri lo foju han pe olujẹjọ jẹbi ẹsun tijọba fi kan an, nitori ẹrọ kan to maa n ṣafihan ibi ti foonu ba wọlẹ si nijọba fi wa a ri, ti wọn si mu un. Nigba to si tilẹ ti jẹwọ pe oun huwa naa, ki ile-ẹjọ da sẹria to ba yẹ fun un ni.
Eyi ni Adajọ Ogongo fi ju Samuel sẹwọn ọdun kan lai saaye owo itanran rara.