Adajọ ju Sharafadeen sẹwọn, awọn ero Mecca lo lu ni jibiti

Adewale Adeoye

Iwaju Onidaajọ Oyindamọla Ọgala, tile-ẹjọ giga kan niluu Eko, ni wọn wọ baale ile kan, Sharafadeen Irọrun, lọ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii. Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe oun pẹlu awọn kan tawọn ọlọpaa ipinlẹ Eko n wa bayii parọ gba miliọnu meje aabo Naira lọwọ awọn araalu kan l’Ekoo, lati ba wọn ṣeto irinajo lọ siluu Mecca, lorileede Saudi Arabia, lọdun to kọja yii, ṣugbọn ti wọn pada kọju wọn soorun alẹ nigbẹyin.

ALAROYE gbọ pe ninu oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, ni wọn kọkọ foju olujẹjọ ọhun bale-ẹjọ, ti wọn si fẹsun gbaju-ẹ kan an, wọn ni oun pẹlu awọn kan tawọn ọlọpaa ṣi n wa bayii ṣeleri ayọ fawọn eeyan kan pe ileeṣẹ awọn maa ba wọn ṣeto irinajo lọ siluu Mecca, lorileede Saudi Arabia, fun ti Hajj lọdun to kọja, ṣugbọn lẹyin ti wọn ko awọn araalu ọhun jọ tan, wọn gba miliọnu meje aabọ Naira lọwọ wọn, ni wọn ba sa lọ. Ṣugbọn ọwọ awọn agbofinro pada tẹ Sharafadeen, ti wọn si wọ ọ lọ sile-ẹjọ.

Lara ẹsun mẹfa ni wọn fi kan an ni pe: O parọ bantabanta fawọn araalu lati gbowo lọwọ wọn, o ṣe gbaju-ẹ fawọn to fẹẹ lọ si Mẹcca, o gbowo lọwọ awọn eeyan lọna aitọ. Bakan naa ni pe oun pẹlu awọn kan parọ da ileeṣẹ awuruju kan silẹ.  Gbogbo ẹsun ọhun pata ni agbefọba ipinlẹ Eko ni ijiya wa fẹni to ba ṣe bẹẹ labẹ ofin ipinlẹ naa.

Olupẹjọ O.A Azeez to foju to olujẹjọ bale-ẹjọ ni iwa ọdaran gidi ni olujẹjọ atawọn ẹmẹwaa rẹ hu, ijiya nla si gbọdọ wa fun wọn, ko le kọ awọn araalu to ba tun fẹẹ hu iru iwa bẹẹ lẹkọọ pe iwa laabi ko daa.

Adajọ gboṣuba fawọn agbefọba ipinlẹ Eko fun iṣẹ takuntakun ti wọn ṣe nipa ẹjọ naa, o ni pẹlu gbogbo ẹri ti wọn ko wa siwaju oun, ko si awijare kankan fun olujẹjọ nipa ẹsun ti wọn fi kan an.

Adajọ ju olujẹjọ sẹwọn ọdun mẹwaa pẹlu iṣẹ aṣekara lọgba ẹwọn Kirikiri, to wa niluu Eko. Ṣa o, o ni lati inu oṣu Kẹfa, ọdun 2022, ti olujẹjọ ti wa lahaamọ ọgba ẹwọn Kirikiri ni ki wọn ti maa ka ọjọ rẹ.

 

Leave a Reply