Aderohunmu Kazeem
Adajọ Olurẹmi Oguntoyinbo ti ile-ẹjọ giga n’Ikẹja, niluu Eko, ti sọ pe ọkan ninu awọn ọmọ jayejaye ilu Eko, to tun maa n gbe fiimu jade, Ṣeun Ẹgbẹgbẹ, atawọn mẹrin
mi-in, Oyekan Ayọmide, Lawal Kareem, Ọlalekan Yusuff ati Muyideen Shoyọmbọ, ti wọn jọ fẹsun ole kan ni ẹjọ lati jẹ o.
Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, ni adajọ yii gbe ipinu rẹ kalẹ lẹyin to gbọ ẹjọ ti Seun Egbegbe pe ta ko ẹsun ti wọn fi kan an, to si ni ki adajọ fagi le e pe oun ni ejọ lati jẹ.
Adajọ Oguntoyinbo ni awọn ọlọpaa ti fi oriṣiiriṣii ẹri mulẹ to fi han pe wọn ni lati jẹjọ ẹsun bii ogoji ti wọn fi kan wọn.
Lara ẹsun ti Agbefọba, Inocent Anyigor, to waa ṣoju ijọba nile-ẹjọ fi kan wọn ni pe wọn lu awọn ileeṣẹ to maa n ṣe paṣipaarọ owo ilẹ wa si owo ilẹ okeere ta a mọ si Bureau De-Change bii ọgbọn ni jibiti owo ilẹ wa, ti ilẹ okeere loriṣiiriṣii laarin ọdun 2015 si 2017.
Agbefọba naa ṣalaye pe miliọnu mọkandinlogoji naira, (39, 098, 100), ẹgberun lọna aadọsan-an owo dọla ($90,000), ati ẹgberun mejila o le diẹ owo pọun (£12, 550), ni wọn lu jibiti rẹ laarin asiko naa nipa piparọ fun awọn eeyan naa pe awọn ni owo ilẹ okeere ti awọn fẹẹ ṣẹ lọwọ wọn.
Iwa yii ni agbefọba lo lodi labẹ ofin iwa ọdaran ipinlẹ Eko, to si ni ijiya to nipọn.
Nigba ti wọn ka ẹsun naa si awọn olujẹjọ leti, wọn ni awọn ko jẹbi. Eyi lo mu ki Adajọ Oguntoyinbo sun igbẹjọ mi-in si ọjọ kejila, ọsu kin-in-ni, ọdun to n bọ.
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ kẹfa, oṣu kẹwaa, ọdun yii ni awọn Ẹgbẹgbẹ fara han ni kootu, nibi ti wọn ti sọ pe ki adajọ da ẹjọ ti awọn agbofinro pe awọn nu, ko si kede pe awọn ko jẹbi gbogbo ẹsun ti wọn fi kan awọn.
Ṣugbọn adajọ naa ni ẹri ti awọn ọlọpaa ni fi han pe awọn eeyan naa ni ẹjọ lati jẹ. Eyi lo mu ki Adajọ Oguntoyinbo sun igbejọ mi-in si ọjọ kẹjila, oṣu kin-in-ni, ọdun to n bọ.