Faith Adebọla
Gbajugbaju ọdaran to sọ iwa ijinigbe diṣẹ nni, Ọgbẹni Chukwudumeme Onwuamadike, ti inagijẹ rẹ n jẹ Evans, ti gba idajọ ẹwọn gbere.
Ile-ẹjọ giga ipinlẹ Eko kan to fikalẹ siluu Ikẹja, lo da afurasi ọdaran naa lẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan an, to si kede idajọ naa lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji yii.
Lajori ẹsun ti Evans jẹbi rẹ, gẹgẹ bi Adajọ Hakeem Oshodi ṣe ṣalaye lasiko to n gbe idajọ rẹ kalẹ ni pe Evans lo wa nidii bi wọn ṣe ji Ọga agba ileeṣẹ apoogun Maydon Phamaceuticals Limited gbe lọdun diẹ sẹyin. Awọn meji ti wọn jọ huwa buruku naa ni Uchenna Amadi ati Okuchukwu Nwachukwu.
Adajọ naa sọ pe awọn ẹri, fidio atawọn alaye tawọn ẹlẹrii ti olupẹjọ mu wa ṣe ni kootu lasiko igbẹjọ fihan pe ni tododo, awọn ọdaran wọnyi jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn.
Nitori naa, Adajọ Oshodi sọ pe ki awọn mẹtẹẹta ti wọn gbimọ-pọ ṣiṣẹ laabi yii lọọ lo iyooku aye wọn lẹwọn, pẹlu iṣẹ aṣekara.
Ṣugbọn adajọ naa da Ogechi Uchechukwu atawọn aloku ṣọja meji kan ti wọn fẹsun kan wọn papọ, Chilaka Ifeanyi ati Victor Aduba, silẹ, wọn ni ẹri ko fidi ẹ mulẹ pe wọn jẹbi ni tiwọn.
Tẹ o ba gbagbe, lati ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Keji, ọdun 2017, ni wọn ti kọkọ foju awọn afurasi ọdaran yii ba ile-ẹjọ lori ẹsun yii, atigba naa ni wọn si ti wa lakolo ọlọpaa.