Adajọ ni ki Reuben lọọ ṣe Keresi at’ọdun tuntun lẹwọn, eyi lohun to ṣe

Faith Adebọla

Ohun to daju bayii ni pe bi gbogbo eeyan ba n yayọ ọdun Keresi ati ọdun tuntun to wọle de tan yii pẹlu awọn mọlẹbi wọn, ti wọn si n ki ara wọn ku alaja ọdun naa labẹ orule ile koowa wọn, ọrọ ko ri bẹẹ fun gende ẹni ọgbọn ọdun to porukọ ara ẹ ni Reuben Temitọpẹ yii, ahamọ ọgba ẹwọn Kirikiri ni awọn ajọdun wọnyi yoo ti ba a, ibẹ loun yoo si ti ke api niu yia tiẹ bayii.

Eyi ko ṣẹyin aṣẹ ti adajọ ile-ẹjọ Majisreeti kan to fikalẹ siluu Ikẹja, nipinlẹ Eko, pa lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrin, oṣu Kejila yii, pe kawọn agbofinro ṣi taari afurasi ọdaran naa sahaamọ ẹwọn Kirikiri titi di ọjọ igbẹjọ mi-in, eyi ti yoo waye lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2024, latari ẹsun ti wọn fi kan an pe o ji ọmọọdun mẹtala gbe, ko si fi mọ bẹẹ, o tun fipa ba ọmọbinrin ti ko ti i tojuu bọ naa laṣepọ lakata rẹ, kọwọ palaba rẹ too segi.

Gẹgẹ bi agbefọba, DSP Kẹhinde Ajayi, ṣe ṣalaye ni kootu, ogunjọ, oṣu Kọkanla, ọdun yii, ni wọn lafurasi naa huwa arufin ọhun nile rẹ to wa lagbegbe Meiran, Alagbado, nipinlẹ Eko.

Ẹsun marun-un ọtọọtọ ni wọn fi kan Temitọpẹ, lara rẹ si ni pe o ji ọmọọlọmọ gbe, o ni ibalopọ tulaasi pẹlu ọmọbinrin ti ko ti i pe ọdun mejidinlogun, bẹẹ ni wọn lo n ko oogun abẹnugọngọ kiri bii Fadeyi oloro, atawọn ẹsun mi-in.

Ajayi ni iwadii tawọn ọlọpaa ṣe ti fidi ẹ mulẹ pe oogun abẹnugọngọ ni jagunlabi yii fi ba ọmọbinrin naa sọrọ, wọn ni niṣe lo paṣẹ fun un titi to fi huwa ọdaran pẹlu ọmọ naa.

Wọn tun ṣalaye pe Opopona Bankọle Ọlanrewaju, nitosi Agas Dalemọ, lagbegbe Alakukọ, ni ile ọmọbinrin yii wa, ibẹ lo n gbe, ibẹ naa si ni Temitọpẹ ti ji i gbe, to fi gbe e lọ sile rẹ ni Alagbado, to si ṣe ọmọ ọhun yankan-yankan kọwọ too tẹ ẹ.

Wọn lo tun fa ibọn yọ sọmọbinrin naa lasiko to fẹẹ fipa ba a laṣepọ, o si paṣẹ fun un pe ko gbọdọ gbin tabi pariwo, aijẹ bẹẹ, yoo fiku ṣefa jẹ ni.

Gbogbo ẹsun wọnyi ni wọn lo ta ko isọri kẹtalelaaadoje (133), isọri ojilerugba o din mẹjọ (232) isọri ọtalerugba (260) ati ọrinlerugba o din mẹta (277) ninu iwe ofin iwa ọdaran ti ipinlẹ Eko, tọdun 2015.

Bo tilẹ jẹ pe Reuben loun ko jẹbi awọn ẹsun wọnyi, Adajọ Abilekọ E. Kubeinjẹ, ni ki wọn lọọ fi i pamọ si Kirikiri titi di ọjọ igbẹjọ to n bọ, ki wọn si ko faili ẹsun rẹ lọ sọdọ ajọ to n gba awọn adajọ nimọran fun itọsọna wọn.

Leave a Reply