Florence Babaṣọla
Adajọ ile-ẹjọ giga kan niluu Oṣogbo, Onidaajọ Ọlayinka Ayọọla, lo dajọ pe awọn olujẹjọ ti fidi ẹsun ti wọn fi kan Tunde mulẹ daadaa, nitori naa, ko lọọ lo iyooku ọjọ aye rẹ lẹwọn.
Ọjọ karun-un, oṣu kẹwaa, ọdun 2012, la gbọ pe Tunde huwa naa laduugbo ti wọn n gbe ni Owode, Igbọna, niluu Oṣogbo.
Olujẹjọ, ẹni ti iya rẹ n lọ ẹrọ-ata, ti oun naa si n ṣe soobata nibẹ, lo ri ọmọ naa ati ẹgbọn rẹ ti wọn n ṣere niwajuu ita. O fa ọmọdebinrin naa lọwọ kuro lọdọ ẹgbọn rẹ, o si mu u lọ sinu ile igbọnsẹ wọn.
O fọwọ bo ọmọ naa lẹnu, o si fipa ba a lo pọ, lẹyin naa lo sọ fun ọmọ naa pe ko gbọdọ sọ ohun to ṣẹlẹ fun ẹnikẹni nitori pe alubami ni iya rẹ yoo na an.
Nigba to di ọjọ keji ti ọmọ yii ko le jokoo daadaa lasiko to n kirun, ni iya rẹ, Sadiat Adejumọ, ba beere lọwọ rẹ pe ki lo ṣẹlẹ si i, o si jẹwọ gbogbo nnkan ti olujẹjọ ṣe fun un, wọn si lọọ fi ọrọ naa to ọlọpaa leti.
Agbẹjọro to n ṣe ẹjọ naa lati ileeṣẹ eto idajọ l’Ọṣun, Barisita Mosunmọla Ogunkọla, fi ẹsun mẹta kan olujẹjọ, ti wọn si nijiya labẹ ipin ọtalelọọọdunrun o din meji, ọtalelọọọdunrun ati ojilelugba o din meji abala ikẹrinlelọgbọn ofin iwa ọdaran ti ọdun 2002 tipinlẹ Ọṣun n lo.
Lasiko ti igbẹjọ naa n lọ lọwọ, ẹlẹrii mẹfa ọtọọtọ ni agbẹjọro ijọba pe, gbogbo wọn ni wọn si jẹrii lati fidi iwa ti olujẹjọ hu si ọmọ naa mulẹ.
Bakan naa lo mu iwe ayẹwo ti Dokita Fẹmi Ala ti ileewosan LAUTECH, to ti di UNIOSUN bayii, ṣe fun ọmọ naa wa si kootu, iyẹn naa si tun fidi ifipabanilopọ ọhun mulẹ.
Agbẹjọro olujẹjọ, T.S. Adegboyega, sọ pe onibara oun ko mọ nnkan kan nipa ẹsun ti wọn fi kan an, o si bẹbẹ pe ki ile-ẹjọ tu u silẹ ko maa lọ lalaafia.
Lẹyin gbogbo atotonu, Onidaajọ Ọlayinka Ayọọla ju olujẹjọ sẹwọn gbere.