Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Ile-ẹjọ giga kan nipinlẹ Ekiti ti paṣẹ pe ki wọn yẹgi fun ọkunrin abọde ṣọja kan, Ọgbẹni Tunde Benson ati ọrẹ rẹ, Olasoji Damilọla, to jẹ ẹni ọdun mejilelọgbọn lori ẹsun idigunjale ti wọn fi kan wọn.
Bakan naa ni kootu tun paṣẹ pe ki Ọgbẹni Ọgbẹsẹtuyi Tunde to jẹ ẹni ọdun mẹrindinlogoji maa lọ sẹwọn gbere fun gbigbimọ-pọ lori ẹsun idigunjale naa.
Ninu idajọ rẹ, Onidaajọ Lekan Ogunmoye sọ pe agbefọba ile-ẹjọ naa to tun jẹ Kọmiṣanna feto idajọ, Ọgbẹni Olawale Fapohunda, ti sa gbogbo ipa lati fi idi ẹsun idigunjale ati igbimọ-pọ ṣiṣẹ ibi ti wọn fi kan awọn ọdaran naa mulẹ lasiko ti igbẹjọ ọhun n lọ lọwọ.
O ṣalaye pe ninu ẹsun idigunjale to jẹ ẹsun keji ti wọn fi kan wọn pe ki wọn lọọ so Tunde Benson to jẹ aloku ṣọja ati Ọlasọji Damilọla rọ titi ti ẹmi yoo fi bọ lẹnu wọn.
Bakan naa lo ran Ọgbẹni Ọgbẹsẹtuyi ti wọn tun fẹsun idigunjale ati igbimọ-pọ lati jale kan lẹwọn gbere.
Awọn ọdaran wọnyi ṣẹ ẹṣẹ naa lọjọ kẹwaa, oṣu kẹta, ọdun 2016. Wọn gbimọ-pọ lati digun ja ile-epo kan to wa lọna Ikẹrẹ-Ekiti, ni Ado-Ekiti, lole.
Bakan naa, ni ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu karun-un, ọdun 2016, Tunde Benson to jẹ ṣọja lakooko ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ, ki wọn too le e kuro ninu iṣẹ ologun ni kete ti igbẹjọ naa bẹrẹ digun ja Ọgbẹni Oluwadare Adebayọ lole nile-epo kan to wa ni Odo-Ado, ni Ado-Ekiti, ti wọn si gba owo to le ni miliọnu kan lọwọ rẹ.
Ẹsun wọnyi ni wọn sọ pe o lodi sofin idigunjale ati gbigbe ibọn tipinlẹ Ekiti n lo.
Ninu awijare rẹ, Oluwadare Adebayọ ti wọn digun ja lole sọ pe ni deede aago mẹfa aabọ irọlẹ ọjọ naa lawọn ọdaran naa wa sile-epo oun, ti wọn si ṣe bii ẹni pe wọn fẹẹ ra epo, ti wọn si fi agbara wọ ibi ti awọn n ko owo pamọ si.
O fi kun un pe ọkan lara awọn adigunjale naa fi idi ibọn gun oun lori, ti oun ko si mọ ibi ti oun wa mọ. Ọkunrin naa ni Benson lo gbe gbogbo owo ti awọn pa lọjọ naa, ọwọ wọn si tẹ Olasọji Damilọla ni tiẹ.
Lati fi idi ẹsun naa mulẹ, Fapohunda pe ẹlẹrii meji, bakan naa lo tun mu apo ikowosi alagbeeka ti foto pelebe meji ati kaadi idanimọ ṣọja naa, Ọgbẹni Tunde Benson, silẹ gẹgẹ bii ẹri.
Awọn ọdaran naa sọrọ lorukọ ara wọn, wọn si pe ẹlẹrii kọọkan.