Faith Adebọla
Ẹwọn fọpawọn ni adajọ ile-ẹjọ giga apapọ to wa l’Abuja fi idajọ rẹ ṣe ninu ẹjọ jibiti lilu ati kiko owo ọba jẹ ti wọn fẹsun rẹ kan alaga igbimọ to n bojuto ọrọ awọn oṣiṣẹ-fẹyinti (Pension Reforms Task Team) nigba kan, Ọgbẹni Abdulrasheed Maina, wọn ni ko lọọ fẹwọn ọdun mọkanlelọgọta (61) jura fun iwa ibajẹ to hu.
Adajọ Okon Abang lo gbe idajọ naa kalẹ lọjọ Aje, Mọnde yii, o ni afurasi ọdaran naa jẹbi marun-un ninu awọn ẹsun ti ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ, jibiti lilu ati ṣiṣẹ owo ilu mọkumọku nni, EFCC (Economic and Financial Crimes Commission) fi kan an.
Ile-ẹjọ naa fidi ẹ mulẹ pe ọdaran yii san owo abẹtẹlẹ fawọn oṣiṣẹ banki Fidelity kan lati ba a ṣi awọn akaunti akanṣe kan pamọ, lai tẹle alakalẹ ijọba, o si tẹ ofin kiko owo ilu ranṣẹ silẹ okeere loju, wọn lo n fi akanti ikọkọ naa gbọn owo awọn oṣiṣẹ-fẹyinti sapo ara rẹ ni.
Nigba ti aṣiri tu, ti wọn yẹ awọn akaunti ikọkọ naa wo, wọn ba obitibiti owo tọkunrin naa ji pamọ ninu wọn, wọn ba miliọnu lọna ọọdunrun naira ninu ọkan (N300 million), miliọnu lọna ẹẹdẹgbẹta naira lo wa ninu omi-in (N500 million), ọkan si tun ni miliọnu kan aabọ ninu (N1.5 million), eyi tọkunrin naa ko le ṣalaye rẹ.
Ile-ẹjọ ni owo tijọba ya sọtọ lati san fawọn oṣiṣẹ-fẹyinti lọkunrin yii ji ko, to si tipa bẹẹ fi ẹtọ ati anfaani to tọ sawọn ti wọn ti fi gbogbo ọjọ aye wọn sin ijọba du wọn.
“Ile-ẹjọ yii fidi ẹ mule pe aropọ owo to ju biliọnu meji naira lọ ni olujẹjọ yii ji ko ni koto ọba, to si pin awọn owo naa kaakiri awọn akaunti awuruju to ṣi sile ifowopamọ kan, ọpọ awọn eeyan lo ti ku lai jere oogun oju wọn ti wọn fi sin ijọba fọpọ ọdun latari iwa ọdaran ati ọdaju tọkunrin yii hu,” Adajọ Abang lo sọ bẹẹ.
Adajọ naa tun sọ pe nigba tawọn ṣiro owo to wa lakaunti ọdaran yii, ati awọn dukia ti aṣiri tu pe o ko jọ laarin asiko to fi wa nipo, wọn ni owo-oṣu ati gbogbo ajẹmọnu to tọ si i ko kaju awọn dukia ati owo naa, bẹẹ lọkunrin naa ko le ṣalaye gidi kan nipa ibi to ti ri aduru owo bẹẹ.
Adajọ ni awọn ẹri to wa niwaju ile-ẹjọ ati ẹri latẹnu awọn oṣiṣẹ banki atawọn tọrọ kan ti fidi ẹ mulẹ pe iwa ole, jibiti, iwa ibajẹ ati ikowojẹ ni Maina hu, eyi to lodi sofin ilẹ wa.
Wọn lo jẹbi ẹsun keji, ikẹta, ikẹfa, ikeje, ikẹsan-an ati ikẹwaa.
Adajọ tun ni ẹbẹ ti agbẹjọro olujẹjọ naa n bẹ ile-ẹjọ pe ki wọn ṣiju aanu wo onibaara oun tun fidi ẹ mulẹ pe loootọ lọkunrin yii huwa abosi ti wọn fi kan an, lo ba paṣẹ pe ki ọkunrin naa lọọ fi aropọ ẹwọn ọdun mọkanlelọgọta (61) jura, ṣugbọn nitori yoo maa ṣẹwọn naa papọ lẹẹkan naa ni, ọdun mẹjọ pere ni yoo fi faṣọ pempe roko ọba.