Adajọ ti Abdulgafar, ayederu lọọya to n gba awọn araalu loju lẹwọn

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Omọkunrin kan, Abdulgafar Ayanrinde, ladajọ ile-ẹjọ Majisreeti kan niluu Oṣogbo, ti ju sẹwọn ọdun mẹfa lori ẹsun pe o n pe ara rẹ ni amofin ati amofin agba lati fi lu awọn araalu ni jibiti owo.

Gafar, ẹni ti a gbọ pe ipele ọlọdun keji lo ti duro ni ẹka imọ ofin ni Fasiti Ibadan, ni ọwọ ajọ Sifu Difẹnsi ipinlẹ Ọṣun tẹ loṣu Karun-un, ọdun yii.

Nigba naa lọhun-un, iwadii wọn fidi rẹ mulẹ pe ṣe ni Gafar yoo wọ aṣọ amofin pẹlu fila wọn, to ba ti wọnu kootu ni yoo ki gbogbo awọn amofin to ba ba nibẹ, eyi ni ko si jẹ ki wọn fura si i titi to fi ṣe eyi ti akara iwa ibajẹ rẹ fi tu sepo.

Agbẹjoro fun ajọ sifu difẹnsi, T. J. Ajayi, ṣalaye fun kootu pe lọjọ kejilelogun, oṣu Karun-un, ọdun yii, ni olujẹjọ tun lọ si ile-ẹjọ giga ipinlẹ Ọṣun to wa niluu Oṣogbo, to si gba ẹgbẹrun lọna aadọjọ Naira lọwọ oniPOS kan lẹyin to ṣe bii amofin to waa ṣiṣẹ nibẹ.

Ajayi ni ọkunrin naa ti lu eeyan marun-un ni jibiti lẹyin to pe ara rẹ ni amofin agba (Senior Advocate of Nigeria), to si tun ji foonu kan ti owo rẹ to ẹgbẹrun lọna ọtalenirinwo o din mẹwaa Naira.

Abdulgafar, ẹni ti ko ni agbẹjọro kankan, sọ pe oun ko jẹbi gbogbo ẹsun ti wọn fi kan oun.

Ninu idajọ rẹ, Onidaajọ M. A. Ọlatunji sọ pe olujẹjọ jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan an, nitori naa, yoo ṣe ẹwọn ọdun mẹta fun ẹsun akọkọ, yoo si ṣe ọdun mẹta fun ẹsun keji.

Adajọ paṣẹ pe ki wọn tiransifaa ẹgbẹrun lọna aadọjọ Naira ti wọn ba ninu akanti olujẹjọ fun ọkan lara awọn to ti lu ni jibiti; Adeoye Iyanu,. Bakan naa lo ni ki awọn alaamojuto ọgba ẹwọn to n lọ ri i pe o ni anfaani lati kawe si i lasiko ti yoo fi wa pẹlu wọn.

Nigba to n sọrọ lori igbẹjọ naa, Kọmandanti ajọ sifu difẹnsi l’Ọṣun, CC Agboọla Sunday, ke si awọn obi ati alagbatọ lati mojuto awọn ọmọ wọn daadaa, o si rọ awọn ọdọ lati lo asiko ati ọgbọn wọn fun awọn nnkan to ṣee ri mọ ọmọluabi, yatọ si iwa buburu.

Leave a Reply