Florence Babasola, Oṣogbo
Ọkunrin ẹni ọdun mejilelọgbọn kan, Babarinde Muritala, ladajọ ile-ẹjọ giga tijọba apapọ to wa niluu Oṣogbo ti sọ sẹwọn ọdun kan bayii lori ẹsun pe wọn ka igbo (Indian hemp) mọ ọn lọwọ.
Ajọ to n gbogun ti lilo oogun oloro (NDLEA), lo wọ Muritala lọ si kootu. Agbẹnusọ fun ajọ naa, Ogaga Azuigo, sọ fun kootu pe baagi igbo meji ti iwọn wọn din diẹ ni kilogiraamu marun-un ni wọn ba nile olujẹjọ labule Akinlalu, niluu Mọdakẹkẹ.
Azuigo pe awọn ẹlẹrii mẹta lati fidi ẹsun naa mulẹ. Ninu awijare Muritala, o ni loootọ loun n mu igbo, ṣugbọn ki i ṣe oun loun ni apo igbo meji ti ajọ NDLEA sọ pe awọn ba lakata oun.
Agbẹjọro fun olujẹjọ, D. D. Adegbọla, rọ ile-ẹjọ lati ṣiju aanu wo o, ki wọn si tu u silẹ lalaafia.
Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Onidaajọ Peter Lifu sọ pe niwọn igba ti olujẹjọ ti jẹwọ pe oun maa n mugbo, ko si ani-ani, oun lo ni awọn apo igbo mejeeji.
Nitori naa, Lifu ju Muritala si ẹwọn ọdun kan gbako, o ni ki kika ọjọ ẹwọn ọhun bẹrẹ loṣu keji ti wọn ti kọkọ gbe e wa si kootu.