Adajọ ti ju Temitọpẹ sẹwọn ọdun mẹrinla

Adewale Adeoye

Adajọ ile-ẹjọ giga kan lagbegbe Tafawa Balewa, niluu Eko, Onidaajọ Yetunde Adesanya, ti ni ki Temitope Olowo lọọ fẹwọn ọdun mẹrinla jura, ẹsun idigunjale ni wọn fi kan an. Oun paapaa ko fi akoko adajọ ṣofo to fi jẹwọ pe loootọ loun jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun.

Ẹsun kan ṣoṣo to ni i ṣe pẹlu igbiyanju lati digunja Ọgbẹni Desmond lole nile rẹ ni wọn fi kan an, eyi ti agbefọba sọ pe o lodi sofin ipinlẹ Eko, o si ni ijiya ninu.

ALAROYE gbọ pe, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kọkanla, ọdun 2018, ni wọn ti kọkọ foju Olowo bale-ẹjọ ọhun, ti wọn si fẹsun idigunjale kan an pe o fẹẹ ja Ọgbẹni Desmond Ifeanyi to n gbe laduugbo Akowonjọ, lole dukia rẹ, ṣugbọn ti ọwọ pada tẹ ẹ.

Nigba to maa fi di Ọjọruu, Wesidee, ọjọ karun-un, oṣu yii, ti wọn tun foju rẹ bale-ẹjọ ni lọọya J.I Osagede to gba ẹnu Olowo sọrọ nile-ẹjọ ọhun rawọ ẹbẹ si adajọ ile-ẹjọ naa pe ko siju aanu wo onibaara oun.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Onidaajọ Adesanya paṣẹ pe ki Olowo lọọ ṣẹwọn ọdun mẹrinla ninu ọkan lara ọgba ẹwọn to wa niluu Eko.

Bakan naa lo ni ki wọn bẹrẹ si i ka ọdun rẹ lati ọjọ kẹrindinlogun, osu Kẹwaa, ọdun 2017, to ti wa lọgba ẹwọn ọhun.

 

 

Leave a Reply