Adajọ ti ni ki wọn lọọ yẹgi fun Ayuba to pa tọkọ-tiyawo l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Adajọ ile-ẹjọ giga keje to wa l’Akurẹ, ti dajo iku fawọn ọrẹ meji kan, Ayuba Idris ati Tasur Abubakar, lori jijẹbi ẹsun idigunjale pẹlu ipaniyan ti wọn fi kan wọn.

Awọn ọdaran mejeeji ni wọn fẹsun kan pe wọn ṣeku pa tọkọ-taya kan, Kwaku Richard Kwakye ati  Abilekọ Tọpẹ Kwakye, lasiko ti wọn lọọ ka wọn mọle wọn to wa ninu Ọjọmọ Akintan Estate, eyi to wa lagbegbe Olu Foam, niluu Akurẹ, ni nnkan bii aago mẹjọ aabọ alẹ ọjọ kin-in-ni, oṣu Karun-un, ọdun 2019.

Agbẹnusọ fun ijọba, Amofin John Dada, ṣalaye pe ọkan-o-jọkan awọn nnkan ija oloro lawọn ọdaran ọhun mu lọwọ lọjọ iṣẹlẹ naa, o ni lẹyin ti wọn digun ja awọn tọkọ-taya naa lole tan ni wọn tun fi okun fun wọn lọrun pa.

Lara awọn ẹsun ti wọn ka si Ayuba ati ọrẹ rẹ lẹsẹ lasiko igbẹjọ ni, gbigbimọpọ ṣiṣẹ ibi, idigunjale, ṣíṣe amulo nnkan ija oloro ati ipaniyan. Awọn ẹsun wọnyi ni agbẹnusọ fun ijọba juwe bii eyi to ta ko abala kẹfa, (ila kin-in-ni ati ekeji), okoole-lọọọdunrun le mẹrin (324) ati okoo-le-lọọọdunrun din ẹyọ kan (319) ninu akanṣe iwe ofin Naijiria ti ọdun 2004.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ laaarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yi,i, Onidaajọ William Ọlamide fagi le meji lara awọn ẹsun ti wọn fi kan awọn ọdaran naa pẹlu bo ṣe ni awọn to jẹ olupẹjọ kuna lati fidi awọn ẹsun naa mulẹ daadaa.

Onidaajọ Olamide ni oun ju awọn mejeeji sẹwọn ọdun meje fun jijẹbi ẹsun kẹta eyi ti i ṣe gbigbimọpọ ṣiṣẹ ibi, lẹyin eyi lo tun paṣẹ ki wọn lọọ yẹgi fun wọn titi ti ẹmi yoo fi bọ lara wọn lori pe wọn jẹbi ẹsun kẹrin ati ikarun-un, iyẹn ẹsun idigunjale ati ipaniyan.

Leave a Reply