Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti
Onidaajọ Adekunle Adelẹyẹ tile-ẹjọ giga ilu Ado-Ekiti ti ṣedajọ iku fawọn meji kan, Adekunle Ọshọ ati Chinedu Ugwu, lori ẹsun idigunjale.
Adekunle to jẹ ẹni ọdun mọkanlelọgbọn ati Chinedu toun jẹ ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn ni wọn fẹsun kan pe wọn digun ja Oloye Ojo Gbenga lole lọjọ kẹrinla, oṣu kọkanla, ọdun 2014, lagbegbe Oke-Ila, l’Ado-Ekiti.
Gẹgẹ bi akọsilẹ kootu ọhun ṣe sọ, ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Camry kan towo ẹ to miliọnu mẹta ati ẹgbẹrun lọna ọọdunrun naira (N3.3m) lawọn ọdaran naa gba lọwọ Oloye Ojo, bẹẹ ni wọn gba ẹgbẹrun lọna aadọjọ naira (N150,000).
Ẹni ti wọn ja lole ṣalaye fun kootu pe ile loun n lọ lọjọ naa pẹlu mọto, boun si ṣe debi gegele kan lawọn eeyan naa yọ soun, bẹẹ ni wọn wọ oun bọ silẹ, wọn si yinbọn foun lẹsẹ ki wọn too gbe mọto ati owo sa lọ.
Aṣoju ijọba to rojọ ta ko awọn eeyan naa, Gbemiga Adaramọla, sọ pe wọn digun jale pẹlu ibọn, eyi to lodi si ofin ibọn lilo tijọba apapọ ṣagbekalẹ lọdun 2004. Bakan naa lo pe ẹlẹrii mẹta, o si lo mọto tawọn eeyan ọhun gba pẹlu aṣọ meji ati owo to le ni ẹgbẹrun mẹrinlelọgọrin (84,700) gẹgẹ bii ẹri.
Lọọya awọn olujẹjọ, Amofin Yinka Ọpaleke, ṣe atotonu tiẹ naa, ṣugbọn ko pe ẹlẹrii kankan.
Nigba ti Onidaajọ Adelẹyẹ ṣagbeyẹwo awọn ẹri to wa nilẹ, o ni wọn fidi ẹ mulẹ pe awọn eeyan ọhun huwa naa, wọn si jẹbi labẹ ofin. O waa paṣẹ pe ki wọn lọọ yẹgi fun wọn titi ti ẹmi yoo fi bọ lara wọn.