Faith Adebọla
Ko ti i ju ọjọ meji ti ile-ẹjọ giga ilu Abuja kan paṣẹ pe ki wọn sọ olori ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ wa, IG Usman Alkali Baba, sẹwọn, bo tilẹ jẹ pe wọn lọkunrin naa ti kọri sile-ẹjọ mi-in pe ki wọn ba oun da wọn lọwọ kọ na, kawọn agbofinro ma ti i fi pampẹ ofin gbe oun. Ile-ẹjọ giga mi-in ti tun paṣẹ pe ki wọn taari olori awọn ọmoogun ilẹ wa, iyẹn Chief of Army Staff, Ọgagun Farouk Yahaya, satimọle, wọn lọkunrin naa fọwọ pa idajọ ile-ẹjọ kan loju, ko si sẹni ti ida ofin o le ge, teeyan ba foju di i.
Lọtẹ yii, ilu Minna, nipinlẹ Niger, nidajọ naa ti wa, ibẹ nile-ejọ giga apapọ to paṣẹ naa l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ ki-in-ni, oṣu Kejila yii, fikalẹ si.
Ẹjọ kan ti nọmba rẹ jẹ NSHC/225/2019 eyi ti Ọgbẹni Adamu Makam atawọn mejilelogun mi-in pe ta ko gomina ipinlẹ Niger atawọn mẹfa mi-in, lo mu ki olupẹjọ pada si kootu naa, to si rawọ ẹbẹ si adajọ pe ki wọn jọ, ki wọn ba oun paṣẹ fun ọga agba ileeṣẹ ologun ohun lati bọwọ fun aṣẹ ile-ẹjọ.
Mohammed Liman, to ṣoju fun olupẹjọ sọ pe niṣe ni ileeṣẹ ologun ilẹ wa ati ọgagun ọhun kọti ọgbọyin si idajọ ile-ẹjọ giga naa, eyi to waye lọjọ kejila, oṣu Kẹwaa, ọdun 2022. Beera ba si fi ni pegi, aa wọn ọn danu ni, o ni kile-ẹjọ sọ ọ sahaamọ tori ẹ.
Loju-ẹsẹ, Adajọ Halima Abdulmalik, alaga ile-ẹjọ naa gbe idajọ rẹ kalẹ, o ni: “Ile-ẹjọ yii pa a laṣẹ pe ki wọn gbe olori awọn ọmoogun ilẹ wa, Farouk Yahaya, ati kọmanda eto idanilẹkọọ ati ilana ologun (TRADOC) to wa niluu Minna, awọn mejeeji yii ti wọn jẹ olujẹjọ kẹfa ati ikeje, ki wọn gbe wọn ju sahaamọ ọgba ẹwọn lai sọsẹ latari bi wọn ṣe foju di idajọ ati aṣẹ tile-ẹjọ yii pa fun wọn lọjọ kejila, oṣu Kẹwaa, ọdun 2022.
“Mo pa a laṣẹ pe ahamọ naa ni ki wọn wa titi digba ti wọn ko ba ri ile-ẹjọ fin ati idajọ fin mọ,” bẹẹ lo sun igbẹjọ to kan si ọjọ kẹjọ, oṣu Kejila yii.
A oo ranti pe Tusidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kọkanla, to kọja, nile-ẹjọ giga apapọ kan l’Abuja sọ ọga patapata ileeṣẹ ọlọpaa sẹwọn lori ẹsun to jọra pẹlu eyi, wọn lo foju dile-ẹjọ, ko ṣiṣẹ lori aṣẹ ti wọn pa fun un ati ileeṣẹ ọlọpaa to n ṣolori rẹ.
Ko si ti i ju ọsẹ kan ṣaaju eyi lọ ti ile-ẹjọ giga ilu Abuja kan gbe iru idajọ bẹẹ kalẹ lodi si ọga agba ajọ to n gbogun tiwa ṣiṣẹ owo ilu mọkumọku, EFCC, Ọgbẹni Abdulrasheed Bawa, wọn loun naa ri ile-ẹjọ fin ni, ni wọn ba sọ ọ si keremọnje, titi ti yoo fi ṣe ohun ti kootu pa laṣẹ.