Nibi idibo ẹgbẹ oṣelu PDP ipinlẹ Ondo to waye lonii niluu Akurẹ, nipinlẹ Ondo, ni awọn olukopa ti dibo yan Họarebu Fatai Adams gẹgẹ bii alaga ẹgbẹ naa tuntun.
Lasiko ibo to waye naa ni Fatai ti fi ẹyin awọn oludije ẹgbẹ ẹ gbolẹ pẹlu bo ṣe ni ibo ẹgbẹrun kan ati ọọdunrun le metalelogoji (1, 443), nigba ti alatako rẹ to sun mọ ọn ju, Alongẹ Denis, ni ọọdunrun ati mọkandinlaaadọrin (369). Ibo mẹtalelaaadọta ni wọn fagi le.
Lẹyin ti wọn ka ibo tan ni wọn kede Adams gẹgẹ bii alaga tuntun fun ẹgbẹ PDP l’Ondo.