Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Lati le mọ iru iku to pa Timothy Adegoke, akẹkọọ Fasiti Ifẹ to doloogbe, Kọmiṣanna ọlọpaa, Wale Ọlọkọde, ti sọ pe ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii ni awọn dokita yoo ṣe ayẹwo oku rẹ.
Adegoke lo gba yara ni otẹẹli Hilton, niluu Ileefẹ, lọjọ keje, oṣu kọkanla, ọdun yii, lasiko to lọ fun idanwo ifimọkunmọ ni OAU Distance Learning Centre, to wa niluu Moro, latigba naa lo si ti di awati.
Alaga ileetura naa, Dokita Ramon Adegoke Adedoyin, ati mẹfa lara awọn oṣiṣẹ rẹ ni wọn ti wa lakolo ọlọpaa, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kọkanla yii, si ni awọn ọlọpaa ri oku Timothy nibi ti wọn sin in si.
Ahesọ to kọkọ n lọ kaakiri ni pe ileegbokuu-pamọ-si OAUTHC, ni oku Timothy wa fun ayẹwo, ṣugbọn Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, sọ pe ileegbokuu-pamọ-si LAUTECH, niluu Oṣogbo, lo wa.
Lori ayẹwo si oku naa, Ọlọkọde ṣalaye pe ọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja, lo yẹ ki ayẹwo naa ti waye, ṣugbọn awọn mọlẹbi oloogbe sọ pe awọn fẹ ki akọṣẹmọṣẹ kan ṣoju awọn naa nibẹ.
O ni awọn reti wọn titi ti ilẹ fi ṣu, wọn ko yọju, idi si niyẹn ti wọn ko fi ti i ṣe ayẹwo ti gbogbo araalu n foju sọna fun ọhun, awọn si ti mu ọjọ Aje bayii.
Ni ti ahesọ to n lọ pe awọn kan ti kọ iwe lọ si ọdọ ọga agba ọlọpaa patapata lorileede yii lati gba iwe ẹjọ naa lọwọ ileeṣẹ ọlọpaa to wa l’Ọṣun, Ọlọkọde sọ pe oun ko ti i gbọ nipa rẹ rara.
O ni “Olu ileeṣẹ ọlọpaa le gba ọrọ naa lọwọ wa, ko si si nnkan ti mo le ṣe si i, ṣugbọn n ko ti i gbọ pe wọn fẹẹ gba a. Awa n tẹsiwaju ninu iwadii wa, a si fi da gbogbo eeyan loju pe aṣiri ọrọ naa maa tu delẹ”
Ninu iroyin mi-in, awọn akẹkọọ-jade ileewe Oduduwa University ti rọ awọn ọlọpaa lati tete fi otitọ idi ọrọ naa han faraye, ki idajọ ododo si tẹle e.
Atẹjade kan ti Aarẹ wọn, Ọlatunji Ọlayinka, fọwọ si, ṣalaye pe Ileetura Hilton yatọ gedengbe si Oduduwa University.
O ni ileetura Hilton ni Adegoke ti gba yara, ki i ṣe Fasiti Oduduwa, nitori naa, ki awọn eeyan ma ṣe ko ọrọ fasiti naa papọ mọ ti ileetura naa.