Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Igbimọ kan ti Gomina ipinlẹ Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke, gbe kalẹ lati tọpinpin dukia ijọba to wa ni sakaani ijọba to kogba wọle, ti sọ pe mọto ti owo wọn din diẹ ni biliọnu mẹta Naira lo ṣi wa ni sakaani gomina ana, Adegboyega Oyetọla, atawọn alabaaṣiṣẹpọ rẹ.
Nitori idi eyi ni igbimọ ọhun, eyi ti Dokita BT Salam, jẹ alaga rẹ, ṣe paṣẹ pe ki Oyetọla, iyawo rẹ, igbakeji rẹ, awọ kọmiṣanna ti wọn ba a ṣiṣẹ atawọn oludamọran gbogbo da awọn dukia naa pada kiakia.
Ninu atẹjade kan ti Agbẹnusọ fun Gomina Adeleke, Mallam Rasheed Ọlawale, fi sita lo ti ṣalaye pe ṣe lawọn eeyan ọhun ko awọn ọkọ ayọkẹlẹ naa lọ lai si ofin kankan to fun wọn lagbara iru ẹ.
Ọlawale ṣọ siwaju pe ninu iwadii awọn igbimọ naa, ọkọ ayọkẹlẹ mọkanla lo wa ni sakaani Gomina Oyetọla nikan, ninu rẹ si ni Lexus SUV, Toyota Prado SUV atawọn ọkọ nla nla mi-in wa.
O ni iyawo Oyetọla naa ko awọn ọkọ ayọkẹlẹ to jẹ tijọba lọ, bẹẹ ni ọkọ ayọkẹlẹ meje lo wa lọwọ igbakeji gomina ana, Benedict Alabi.
Bakan naa ni wọn ni awọn dukia to jẹ ti ileeṣẹ Osun State Agricultural Development Programme wa lọwo Sẹnetọ Oriolowo to n ṣoju awọn eeyan Iwọ-Oorun Ọṣun lọwọlọwọ,
Igbimọ yii waa paṣẹ pe ki wọn da gbogbo awọn dukia ijọba pada kiakia ko too di pe awọn yoo lo ọwọ ofin lati fi gba a lọwọ wọn.
Ṣugbọn ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọṣun ti sọ pe alawada kẹrikẹri ni awọn igbimọ naa, bẹẹ ni wọn ko si fi ootọ ṣiṣẹ iwadii wọn daadaa.
Ninu atẹjade kan ti Alakooso iroyin wọn, Kọla Ọlabisi, fi sita, o ni awọn igbimọ naa ti kọ ohun ti yoo jẹ abajade wọn ko too di pe gomina gbe wọn kalẹ gan-an.
Ọlabisi fi kun ọrọ rẹ pe gbogbo mọto ti wọn lo wa lọwọ igbakeji Oyetọla ni igbakeji Adeleke ti n lo lọwọlọwọ bayii, eyi to si mu un nira fun eeyan lati gba wọn gbọ.
O ni nipasẹ agbekalẹ ofin ati ọrọ asọye (law and convention), gomina ati igbakeji rẹ lanfaani si awọn ẹtọ kan ti wọn ba ti n kuro nile ijọba, gbogbo rẹ lo si wa ninu akọsilẹ, Oyetọla ati Alabi ko si mu ju awọn nnkan wọnyi lọ.
Ni ti awọn kọmiṣanna atawọn mi-in, Ọlabisi ṣalaye pe gomina ana lo fọwọ si i pe ki wọn maa gbe awọn ọkọ ti wọn n lo tẹlẹ lọ gẹgẹ bii ẹbun fun iṣẹ ribiribi ti wọn ṣe fun ipinlẹ Ọṣun, niwọn igba ti wọn ko lanfaani si owo ifẹyinti tabi owo ajẹmọnu kankan.