Adeleke kọ lẹta si Arẹgbẹṣọla, eyi lohun to kọ sibẹ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Gomina Ademọla Adeleke ti ipinlẹ Ọṣun, ti sọ pe ẹni ti oṣelu ye daradara, to si n gbe oore-ọfẹ to pọ kaakiri pẹlu igboya ni Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla.

Ninu orọ ti Adeleke fi ranṣẹ si Arẹgbẹṣọla layaajọ ayẹyẹ ọjọọbi ọdun kẹtadinlaaadọrin to de oke-eepẹ ni Adeleke ti ṣalaye pe Arẹgbẹṣọla mọ pataki aṣepọ ninu oṣelu, o si mọ bi a ṣee ko awọn eeyan jọ.

Gẹgẹ bi Adeleke, ẹni ti Akọwe funjọba ipinlẹ Ọṣun, Alhaji Teslim Igbalaye, ṣoju fun nibi ayẹyẹ to waye niluu Oṣogbo naa ṣe wi, ‘A wa nibi lati ṣapọnle ogbontagiri ninu oṣelu ilẹ wa, ẹni to ni imọ kikun ninuu bi a ṣe n ko awọn eeyan jọ fun aṣeyọri idibo.

‘Ẹ jẹ ki n sọ fun yin pe Ọgbẹni sin ipinlẹ ati orileede yii tọkantọkan. O ni iriri pupọ, o jẹ aṣaaju rere ninu oṣelu, ẹni to jẹ pe Imọlẹ Adulawọ nikan lo le ba a figagbaga to ba di ọrọ itẹwọgba laarin awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun.

‘Gẹgẹ bii kọmiṣanna tẹlẹ nipinlẹ Eko, Arẹgbẹṣọla fakọyọ. Gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Ọṣun, o ṣewọn agbara rẹ lati mu ipinlẹ yii goke agba, bẹẹ lo gbe ọpọlọpọ igbesẹ akin gẹgẹ bii minisita lorileede yii.

‘Lonii ayẹyẹ ọjọọbi rẹ, inu mi dun lati sọ fun ọ pe ijọba wa ti n pari ọpọlọpọ awọn iṣẹ akanṣe tiṣejọba rẹ dawọ le, ṣugbọn ti ẹni to gbaṣẹ lọwọ rẹ pa ti, bẹrẹ lati ọrọ ilegbee ati bẹẹ bẹẹ lọ.

‘A gbagbọ pe ijọba gbọdọ tẹsiwaju ni, a ni idaniloju pe iṣẹ ti ẹnikẹni ba dawọ le ninu ilu gbọdọ jẹ aṣekun ati imugbooro fun iṣejọba miran. A le sọ pe awọn ogun (legacy) rẹ wa sibẹ, iṣejọba wa si n bomi rin wọn.”

Gomina Adeleke waa gbadura pe ki Ọlọrun fun Arẹgbẹṣọla ni ẹmi gigun to kun fun ibukun ati alaafia.

Leave a Reply