Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Gomina tuntun nipinlẹ Oṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke ti kede orukọ awọn ti yoo jẹ olori oṣiṣẹ lọfiisi rẹ, akọwe ijọba ati agbẹnusọ rẹ.
Ninu atẹjade kan ti gomina fọwọ si lo ti yan Alhaji Kassim Akinlẹyẹ, ọmọ bibi ilu Ẹdẹ, to ti figba kan jẹ alaga ijọba ibilẹ, gẹgẹ biii olori oṣiṣẹ lọfiisi rẹ.
Alhaji Teslim Igbalaye toun naa ti figba kan jẹ alaga ijọba ibilẹ Ọṣogbo ati alaga igbimọ awọn alaga lasiko iṣejọba Ọmọọba Oyinlọla ni Adeleke yan gẹgẹ biii akọwe ijọba. Ọmọ bibi ilu Oṣogbo ni.
Bakan naa ni Adeleke yan Mallam Rasheed Ọlawale, ọmọ bibi ilu Iwo gẹgẹ bii agbẹnusọ funjọba rẹ.
O ni iyansipo naa bẹrẹ loju-ese