Adẹrin-in-poṣonu ṣawada daran n’Ibadan, awọn ọlọpaa ti n wa a

Ọlawale Ajao, Ibadan

O ṣee ṣe ki ọkunrin adẹrin-in-poṣonu to filu Ibadan ṣebugbe nni, Abdullahi Maruff Adisa, ti gbogbo aye mọ si Trinity Guy, ti dero atimọle ọlọpaa, nitori awọn agbofinro naa ti n wa a.

Ki i ṣe pe Adisa jale tabi luuyan ni jibiti, iṣẹ ajé tó yan laayo lo fẹẹ mu un ko si gbaga.

Ninu fidio awada kan tọkunrin naa ju sori ẹrọ ayelujara lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkndinlogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii, lo ti fi iku ṣere, to si fi ẹsin awọn ọmọlẹyin Jesu pa mì-ín-dìn.

Nṣe lọkunrin ara Ibadan yii kunlẹ, to bẹrẹ si i bẹ awọn ẹni airi kan pe ki wọn jọọ, ma ṣe pa oun, o ni oun maa sanwo wọn. Ori ẹbẹ yii lo wa ti obinrin alaṣọ funfun kan to jọ pe o n kọja lọ si ṣọọṣi ti ba a, to si sare kunlẹ wọọ, to bẹrẹ si i gbadura kikankikan fun un pe ki Ọlọrun gba a lọwọ iku ojiji, ki wọn ma ṣe yinbọn pa a bii ẹni pa ẹranko.

Ṣugbọn lojiji lawọn ti Trinity Guy n bẹ, ṣugbọn ti ẹnikẹni ko ri ọhun yinbọn fun un lati inu igbo, to si ṣubu yakata silẹ bii ẹni to ti ku. Nigba naa lobinrin to mura bii wolii yii fo dide lori ikunlẹ, nibi to ti n gbadura, to si bẹrẹ si í fi gbogbo agbara sare lati sa asala fun ẹmi ẹ lọwọ iku ibọn.

Fidio yii ni Alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa lorileede yii, CSP Olumuyiwa Adejọbi, wo to fi binu, o ni niṣe lo yẹ kawọn ọlọpaa mu ọkunrin alawada naa.

Gẹgẹ bo ṣe kọ ọ sori ikanni ayelujara rẹ, “eyi o ba laakaye mu. Mi o ro pe o yẹ kọkunrin yii ṣi wa lominira ara ẹ bayii, o yẹ ki wọn ti mu un.

“Nṣe lo yẹ ki awọn ti iru awọn ere wọnyi ba pa lara maa fẹjọ awọn to n ṣeru ẹ sun awọn alaṣẹ, nitori pupọ ninu awọn ere bẹẹ lo lodi sofin”.

Pẹlu ohun ti CSP ọlọpaa to wọn n pe l’Ọmọọba Adejọbi sọ yii, ta a ba fi rẹni to fẹjọ Trinity Guy sun awọn agbofinro lori awada yii tabi eyikeyii ninu awọn eyi to ti  ṣe sẹyin, tabi ṣugbọn ko si nibẹ, lọgan lawọn ọlọpaa yoo gbe e.

 

 

Leave a Reply