Adigun ti gba ibi to gba waye lọ sọrun o, iya ati ọmọ ni wọn lo n ba lo pọ n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Iyawo ile kan, Bọsẹ Adegoke, pẹlu ọmọ ẹ, Yetunde Adegoke, ti dero ahamọ awọn ọlọpaa ni Iyaganku, n’Ibadan, wọn ni wọn lọwọ ninu iku ọkunrin ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn (25) kan, Adigun, ẹni ta a fi ojulowo orukọ ẹ bo laṣiiri.

Bo tilẹ jẹ pe Adigun ṣaisan ko too j’Ọlọrun nipe, a gbọ pe ibalopọ niya ẹni ọdun mejilelaaadọta (52), to n jẹ Bọsẹ yii pẹlu Yetunde ọmọ rẹ, fi han ọmọkunrin naa leemọ ko too kagbako aisan to pada gbẹmi ẹ ni kekere yii.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, Yetunde, ẹni ọdun mejidinlọgbọn (28), to ti bimọ meji, ṣugbọn ti ko si nile ọkọ, pẹlu Adigun, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn (25), ti ko ti i bimọ kankan ri ni tiẹ ni wọn jọ n fẹra wọn, ti Bọsẹ, to jẹ Iya Yetunde si mọ nipa ẹ.

Eyi ti obinrin fi maa n ko lọ sile ọkọ nigba ti asiko igbeyawo ba to, Adigun lo ṣadeede palẹ ẹru rẹ mọ kuro lọdọ iya ẹ to n gbe, to bẹrẹ si i gbe ile awọn ololufẹ ẹ ninu igboro Ibadan kan naa.

Oloogbe ti lo bii oṣu meji kan ninu ile awọn ọrẹbinrin ẹ ki iya ẹ too mọ ibi to gba lọ lati iye ọjọ yii. Igbiyanju ẹ lati ri i pe ọmọ rẹ yii pada sile ko so eeso rere, n lo ba lọọ fẹjọ sun awọn agbofinro lagọọ ọlọpaa to wa ni Gbagi, n’Ibadan.

Ṣugbọn bi awọn ọlọpaa ṣe da si ọrọ naa to, ibi pẹlẹbẹ lọbẹ fi lelẹ. Niṣe l’Adigun fariga, o ni ibi to wu oun lati maa gbe loun ti de yii, n lawọn gabofinro ba yọwọ yọsẹ lori ọrọ naa nitori ẹni ti wọn n ba fa a ti kọja ọmọọdun mejilelogun (18), o ti kuro lọmọde ti wọn le paṣẹ fun nipa bo ṣe ni lati ṣeto aye ẹ.

Nitori ki ana wọn yii ma baa ṣe maa yọ wọn lẹnu mọ, awọn Adegoke tun mu ọkunrin naa lọ siluu Isẹyin, wọn wa iṣẹ fun un, wọn si rẹnti yara kan fun un sibẹ, ṣe ọmọ bibi ilu naa ni wọn ki laalaa kookoo ọmọ eeyan lorilẹ aye too sọ wọn di ara Ibadan.

Ẹnikan to mọ nipa iṣẹlẹ yii daadaa, ṣugbọn ti ko fẹ ka darukọ oun, ṣalaye pe “Oṣiṣẹ ijọba l’Abilekọ Adegoke. Ko pẹ rara ti wọn gba ile fọmọkunrin yẹn niluu Iṣẹyin ni wọn tiransifaa wumaanu yẹn lati Ibadan lọ si Iṣẹyin, inu yara kan naa to gba fun ọmọkunrin yẹn loun naa n sun pẹlu ẹ.

“Lẹyin oṣu marun-un ti ọmọkunrin yẹn bẹrẹ si i gbe Isẹyin laisan kọ lu u. Abilekọ Adegoke gbe e lọ sileewosan, ṣugbọn ara ẹ ko ti i ya rara ti iya yẹn fi pa a ti sibẹ, ti ko si wẹyin rẹ wo mọ lọsibitu yẹn.

“Kaka ki ara ọmọkunrin yẹn ya, niṣe lailera rẹ n buru si i. Eyi lo mu ki awọn ara ọsibitu yẹn wa iya rẹ kan n’Ibadan, ti iyẹn fi gbe e lọ sọsibitu mi-in n’Ibadan. Ṣugbọn ko lo ju ọjọ meji kan lọ lọsibitu ọhun to fi j’Ọlọrun nipe”.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, nitori ibalopọ ti iya atọmọ n jẹgbadun lara Adigun ni wọn ṣe fẹran rẹ to bẹẹ debi ti wọn fi fẹ ko maa gbe pẹlu awọn.

Wọn l’Oloogbe fẹnu ara ẹ sọ fawọn to sun mọ ọn ko too jade laye pe oun pẹlu Bọsẹ, iya afẹsọna oun jọ maa n sun oorun ifẹ, iyẹn ni pe bo ṣe n ba ọmọ laṣepọ niya papaaa n gbe e sun mọ ọn.

Bo tilẹ jẹ pe akọroyin wa ko lanfaani lati fidi iṣẹlẹ yii mulẹ lẹnu SP Adewale Ọṣifẹṣọ ti i ṣe Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, ẹka ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ ọhun to n ri si iwadii ẹsun ọdaran la gbọ pe Bọsẹ ati Yetunde ọmọ rẹ wa bayii, nibi ti awọn atọpinpin ti n fọrọ wa wọn lẹnu wo nipa iku to pa ọkunrin ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn naa.

Leave a Reply