Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ni nnkan bii aago kan ọsan ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni awọn adigunjale mẹrin kan kọ lu Ọgbẹni Abu Sifau, ninu ọkọ ayọkẹlẹ rẹ lagbegbe Sabo-Oke, niluu Ilọrin, ti wọn si ji owo to to miliọnu mẹfa Naira sa lọ.
ALAROYE, gbọ pe awọn adigunjale naa to mẹrin, ti wọn si bẹrẹ si i yinbọn leralera lati ṣẹru ba awọn eniyan, ti onikaluku si n sa asala fun ẹmi wọn ki wọn too ni anfaani lati da ọkọ ayọkẹlẹ Abu Sifau duro, ti wọn si gbe miliọnu mẹfa lọ ninu ọkọ naa.
Awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe aago kan ọsan ni iṣẹlẹ naa waye, ti awọn adigunjale to to mẹrin niye lo iboju, ti wọn si bẹrẹ si i yinbọn leralera. Ọpọ awọn to n taja ni agbegbe naa ni wọn sa lọ patapata.
Alukoro ọlọpaa ni Kwara, Ọkasanmi Ajayi, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni iwadii n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ ọhun.