Ọlawale Ajao, Ibadan
Nnkan ṣe ninu ọgba Fasiti Ibadan (University of Ibadan, UI) pẹlu bi awọn adigunjale kan ṣe ṣigun wọ ọkan ninu awọn agbegbe ti awọn oṣiṣẹ fasiti ọhun n gbe, ti wọn si yinbọn pa ẹni kan nibẹ lalẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja.
Ẹni ti wọn yinbọn pa yii, Ọgbẹni Vincent Odinko, lo jẹ ọkọ fun obinrin kan to n ṣiṣẹ ninu ọgba Fasiti Ibadan, ṣugbọn nileeṣẹ ti wọn n pe ni National Examination council (NECO), ajọ to n ṣakoso idanwo aṣejade ileewe girama loun funra rẹ ti n ṣiṣẹ lọfiisi ajọ naa to wa laduugbo Agodi, n’Ibadan.
Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, ori ẹrọ agbeletan l’Ọgbẹni Odinko ti n ṣiṣẹ lọwọ ninu ile ti oun pẹlu iyawo atawọn ọmọ rẹ n gbe ko too di pe awọn afẹmiṣofo naa ya lu u lojiji, ti wọn si ṣi i lọwọ iṣẹ.
Ẹrọ agbeletan rẹ ọhun ni wọn kọkọ gbe lẹyin ti wọn gbẹmi ẹ tan. Bakan naa ni wọn ko awọn ẹrọ ibanisọrọ rẹ pẹlu tawọn mọlẹbi ẹ gbogbo lọ.
Alukooro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, SP Adewale Ọṣifẹṣọ, ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o ni wọn ti fi iṣẹlẹ naa to awọn agbofinro leti, iwadii si ti n lọ lọwọ lati ri awọn amookubṣika ẹda naa mu, ki wọn le jiya to ba tọ si wọn labẹ ofin.