Ọlawale Ajao, Ibadan
Inu ibẹrubojo ni awọn eeyan adugbo Ifẹlagba, Adetokun, Ologun Ẹru, to wa ni Idi-Ọsan, nijọba ibilẹ Iddo, niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ wa bayii. Nibi tọrọ naa le de, ko sẹni to le sun oorun asun-diju ninu wọn. Ohun to fa aisun ojiji yii ni bi awọn adigunjalẹ ṣe kọ lẹta si wọn pe awọn n bọ waa ba wọn lalejo o, ki wọn maa reti awọn nipari oṣu Kọkanla yii.
Awọn eeyan adugbo naa ni wọn sọ eyi di mimọ fun awọn oniroyin. Ninu lẹta naa, eyi ti awọn adigunjale naa lẹ kaakiri awọn ile to wa ni adugbo ọhun ni wọn ti kọ ọ pe ki awọn eeyan adugbo yii maa mura awọn silẹ o, nitori awọn n bọ waa digun ja wọn lole nipari oṣu Kọkanla yii. Wọn fi kun un pe ki wọn ma wulẹ daamu ara wọn pe awọn n gbọkan le awọn ọdẹ adugbo yii o. Wọn ni awọn maa kapa awọn ọdẹ yii, ti awọn si maa ṣe wọn bi ọṣẹ ṣe n ṣe oju nitori awọn ni wọn ti n di awọn lọwọ lati ṣe iṣẹ ibi ti awọn fẹẹ ṣe ni adugbo naa latọjọ yii.
Latigba ti awọn eeyan agbegbe naa ti ri awọn iwe ti wọn le kaakiri yii ni wọn ti wa ninu ibẹru, aya wọn n ja gidigidi, ọkan wọn ko si balẹ.
Ọkan ninu awọn agbaagba agbegbe naa to ba akọroyin wa sọrọ sọ pe awọn ti n gbe igbesẹ lori ohun ti wọn kọ naa, ṣugbọn awọn ko fẹẹ sọ igbesẹ ti awọn n gbe jade nitori ọrọ to ni i ṣe pẹlu eto aabo ni.