Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Afaa Tunde Ọlayiwọla tọwọ tẹ pẹlu ori eeyan tutu lọjọ Isẹgun, Tusidee, ọsẹ to kọja, la gbọ pe o ti ku si ahamọ awọn ọlọpaa ti wọn fi i pamọ si.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, Afaa ẹni ọdun marundinlọgọta ọhun ni wọn lo deedee ṣubu lulẹ, to si ku loju-ẹsẹ ninu atimọle to wa lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja.
Titi di asiko yii lọrọ iku afurasi afiniṣetutu ọla naa si n jẹ kayeefi fawọn eeyan pẹlu bi wọn ṣe ni ọkunrin naa kọ lati darukọ ẹni to waa gbe ori ọhun fun un titi to fi ku.
Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja, ni apapọ awọn Musulumi ati Imaamu nijọba ibilẹ Ila Oorun ati Iwọ-Oorun Ondo fi atẹjade kan sita, ninu eyi ti wọn ti kilọ fawọn eeyan lati yee pe afurasi ọhun ni Afaa tabi Musulumi.
Wọn ni awọn ti ṣe iwadii nipa ọkunrin naa daadaa, awọn si ti fidi rẹ mulẹ pe ojulowo babalawo ni i ṣe, ki i ṣe afaa tabi Musulumi tawọn eeyan n pe e.