Bi nnkan ṣe n lọ ninu ẹgbẹ oṣelu APC ipinlẹ Ekiti bayii, afaimọ ni wọn ko ni i le ọkọ ọmọ Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, iyẹn Oyetunde Ojo, kuro ninu ẹgbẹ naa, koda ko jẹ fun igba diẹ pere. Oun nikan kọ ni wọn yoo le ninu ẹgbẹ ọhun paapaa, nitori ẹni kan to tun sun mọ Tinubu, to si ti jẹ aṣofin tẹlẹ ri, Babafẹmi Ojudu, paapaa le fara ko o. Ẹsun pe wọn n tapa sofin ẹgbẹ ni wọn fi kan wọn, wọn si ti gbe igbimọ ti yoo jẹ wọn niya dide.
Ohun to ṣẹle ni pe ninu oṣu kẹfa ọdun yii ti wọn gbe igbimọ fidihẹẹ kalẹ niluu Abuja lati ṣakoso APC titi ti wọn yoo fi yanju ede-aiyede to bẹ silẹ laarin wọn, ofin akọkọ ti wọn ṣe ni pe gbogbo ẹni yoowu to ba pe ẹgbẹ yii tabi awọn alaṣẹ ẹ lẹjọ, to si jẹ ọmọ ẹgbẹ, gbọdọ lọọ fawe ẹjọ naa ya ni kootu kiakia, bi bẹe kọ wọn yoo da sẹria fun tọhun ninu ẹgbẹ wọn. Ṣugbọn lati igba naa, awọn to pe ẹgbẹ wọn lẹjọ ni Ekiti ko ti i fawe ẹjọ ya, ninu wọn si n sọ pe awọn ko ni i gba rara. Ninu awọn ti wọn fi ẹsun eyi kan ni ana Tinubu wa, ti Ojudu wa, ati Ọmowe Wọle Oluyẹde, Ayọ Ajibade, pẹlu Fẹmi Adelẹyẹ.
Alukoro ẹgbẹ APC ipinlẹ naa, Sam Oluwalana, sọ ni Ado Ekiti lanaa pe awọn ti gbe igbimọ dide lori ọrọ yii, gẹgẹ bii aṣẹ ti wọn pa fawọn lati olu ile ẹgbẹ wọn niluu Abuja. O ni idi ti awọn fi gbe igbimọ naa kalẹ ni pe bo tilẹ jẹ lati ọjọ kẹẹẹdọgbọn oṣu kẹfa ni sẹkiteeria ẹgbẹ awọn lapapọ ti ni ki awọn ti wọn ba pe ẹgbẹ lẹjọ lọọ jawọ ninu ẹ, ati bi awọn ti ṣe jirẹbẹ titi fun awọn ti ọrọ yii ba wi lEkiti, awọn eeyan naa ko ṣiwọ ninu ohun ti wọn n ṣe. O ni nidii eyi lawọn ṣe gbe igbimọ yii dide lati bẹrẹ eto bi wọn yoo ṣe da iru awọn eeyan bẹe duro ninu ẹgbẹ awọn.
Aarin ọjo mọkandinlogun ni igbimọ yii yoo fi ṣiṣẹ ti wọn gbe le wọn lọwọ yii, ohun ti yoo si ti ẹyin rẹ jade, ko ti i sẹni to le sọ.