Monisọla Saka
Awọn igbakeji oludije sipo Aarẹ lẹgbẹ oṣelu PDP ati Labour, Ifeanyi Okowa ati Datti Baba-Ahmed, ti sọ pe ko si ootọ kankan ninu eto idibo ti wọn di lọjọ Satide to lọ yii, nitori idi eyi, ki Mahmood Yakubu ti i ṣe ọga agba ajọ INEC fipo silẹ, ki wọn si ṣeto idibo tuntun mi-in ni kiakia.
Nibi ipade apero to waye niluu Abuja, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Keji yii, lawọn mejeeji ti sọ bẹẹ.
Ninu ipade apero tawọn ẹgbẹ alatako mẹta ọhun ṣe, iyẹn ẹgbẹ oṣelu PDP, Labour Party ati African Democratic Congress, ADC, ni wọn ti sọ fun Alaga ajọ eleto idibo, INEC, Mahmood Yakubu, lati sun si ẹgbẹ kan, latari magomago ti wọn lo waye nibi ibo aarẹ atawọn aṣofin to waye lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii jẹ.
Ninu ọrọ rẹ, Gomina ipinlẹ Delta, to tun jẹ igbakeji oludije funpo aarẹ lẹgbẹ oṣelu PDP, Ifeanyi Okowa, sọ pe wahala, agbelẹrọ ati ibo to kun fun abosi ati magomago leto idibo ọhun, ki i ṣe eto idibo to lọ nirọwọrọsẹ gẹgẹ bi wọn ṣe ti sọ fawọn araalu.
Amọ ṣa o, awọn ẹgbẹ oṣelu APC naa ti faju ro si ọrọ tawọn ẹgbẹ alatako mẹtẹẹta ọhun, iyẹn PDP, Labour Party ati ADC sọ nitori bi wọn ṣe sọ pe ki Mahmood Yakubu, ti i ṣe alaga ajọ eleto idibo nilẹ yii kọwe fipo silẹ, ki wọn si tun ibo ọhun di jake-jado orilẹ-ede yii.
Ninu ipade oniroyin tawọn ẹgbẹ oṣelu APC naa pe lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ni wọn ti sọ pe ko si kọnu-n-kọhọ kankan ninu ibo aarẹ ati tawọn aṣofin to waye lọjọ Abamẹta, Satide, o si daa to niwọnba, gẹgẹ bii ireti awọn eeyan.
Festus Keyamo, ti i ṣe agbẹnusọ igbimọ eleto idibo ẹgbẹ oṣelu APC, sọ pe ko tọna labẹ ofin lati pe fun idaduro eto idibo, nigba ti wọn o ti i ka esi idibo tan, tabi ki wọn tilẹ kede ẹni to wọle sipo aarẹ paapaa.
O ni, “Wọn tilẹ lọ n pe Aarẹ Muhammadu Buhari pe ko waa da si ọrọ esi ibo ti wọn n ka. Akọkọ ni pe, nnkan tẹ ẹ n beere fun yẹn ko ṣee ṣe labẹ ofin”.
Keyamo to tun jẹ Minisita kekere fọrọ iṣẹ ati igbanisiṣẹ lorilẹ-ede yii fi kun un pe awọn ẹgbẹ alatako ọhun n ta ko ofin eto idibo ilẹ Naijiria ni, nitori esi idibo tawọn ọga eleto idibo ipinlẹ kọọkan ko jọ, alaga ajọ eleto idibo funra ẹ ko le tọwọ bọ ọ.
O ni, “Nigba tawọn esi idibo ọhun ba ti de ibi ti wọn ti n ṣakojọ ibo, ti wọn ti n kede ẹ faye gbọ, alaga ajọ INEC ko lagbara labẹ ofin lati yiri nnkan tawọn ọga eleto idibo ipinlẹ kọọkan ti ṣe wo.”
O tẹsiwaju pe ipele wọọdu, ijọba ibilẹ ati ipinlẹ kọọkan, lo yẹ ki wọn ti yanju ikunsinu ati ariwisi yoowu ti wọn ba ni. O waa la a mọlẹ fun wọn pe ile-ẹjọ to n gbọ ẹsun ibo, (Tribunal), nikan lo le da si ọrọ naa, nitori idi eyi, ki awọn tinu ba n bi, ti wọn ko si fara mọ abajade esi idibo ti wọn n ka, gba ile-ẹjọ lọ, ti wọn ba lẹjọ ti wọn fẹẹ ṣe.