Faith Adebọla
“A jade loni-in nitori gbogbo ọmọ Naijiria, a jade lati le sọ fun ijọba pe owo ti wọn fi kun owo ina ẹlẹntiriiki laipẹ yii ko daa, aba buruku ni, aba ti ko ni i jẹ ki ọpọ anfaani wa sorileede yii, nitori awọn olokoowo ati onileeṣẹ ti wọn n lo ina, ọpọlọpọ wọn ti n tilẹkun, wọn ti palẹ ẹru wọn mọ lo sawọn orileede alamulegbe wa.
“A tun jade nitori awa naa ti ri i pe ijọba to wa lode yii ki i ṣe ijọba to nifẹẹ mẹkunnu lọkan ni ti gidi, ti wọn ba nifẹẹ mẹkunnu ni, ki lo de? Ṣebi a lawọn eeyan kan to lọọ ṣoju wa nileegbimọ aṣofin agba ati aṣoju-ṣofin l’Abuja, a n fi gbogbo ẹnu sọ ọ pe ẹyin eeyan yii, ẹ o lọọ ṣoju fun wa o, ikun ara yin ati ti ẹnu yin lẹ ba lọ. To ba jẹ pe ẹ lọọ ṣoju wa ni, o yẹ kẹ ẹ ti fi awọn eto tijọba n gbe jade yii, kẹẹ maa yẹ eto wọn wo, kẹ ẹ si le maa sọ fun ijọba pe eleyii o daa, awọn ta a n ṣoju fun ko le fẹ eleyii. Ọlọrun aa bi yin, beeyan ko bi yin o.
“A fẹ kẹyin onṣejọba maa ṣe nnkan tawọn araalu aa fi maa ṣadura fun yin ni, ki i ṣe eyi ti wọn maa maa fi epe ranṣẹ si atirandiran yin, tori eleyii tẹ ẹ ṣe yii, epe lo yẹ yin o.”
Eyi lawọn ọrọ rigidi-rigidi to n bọọlẹ bii oko lẹnu olori ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ, Nigeria Labour Congress, NLC, nipinlẹ Eko, Kọmureedi Funmi Ṣeesi, nigba to n ba ikọ tẹlifiṣan AlaroyeonlineTV sọrọ lori iwọde ati ifẹhonuhan ti ẹgbẹ naa gun le lọjọ kẹtala, oṣu Karun-un, ọdun 2024.
Ṣibaṣiba lawọn ọmọ ẹgbẹ ati awọn adari ẹka ẹgbẹ NLC, ati ẹgbẹ awọn olokoowo, Trade Union Congress (TUC), atawọn ẹgbẹ mi-in to wa labẹ wọn pesẹ siwaju olu-ileeṣẹ apinnaka Ikẹja, iyẹn Ikẹja Electricity Distribution Company (IKEDC), to wa ni Alausa, n’Ikẹja, nipinlẹ Eko.
Oriṣiiriṣii akọle lawọn oluwọde naa gbe dani, bẹẹ ni wọn n kọrin ikilọ loniran-iran lati fihan pe awọn ko fara mọ afikun owo ina mọnamọna tijọba ṣẹṣẹ ṣe laipẹ yii.
Ẹgbẹ naa ṣalaye pe arumọjẹ ati ẹtan ni pinpin ti wọn pin awọn onibaara ileeṣẹ ẹlẹntiriiki si isọri mẹrin, Band A, Band B, Band C ati Band D. Wọn ni awọn to wa ni Band A ni owo ina wọn pọ ju, awọn naa si ni wọn n ri ina lo ju lọ, eyi si ti ṣakoba fun ọrọ-aje araalu ti agbara wọn ko gbe iru ẹkunwo gegere bẹẹ.
Abilekọ Ṣessi ni ijọba ko ronu igbe aye irọrun faraalu, o lawọn ko fẹ isọri ti wọn pin yẹlẹyẹlẹ yii, ki wọn pada si bo ṣe wa tẹlẹ, ki owo ina naa si walẹ si ohun ti agbara mẹkunnu le ka, tori ẹtọ araalu ni lati gbadun ina ẹlẹntiriiki. Bẹẹ lo tun sọ pe ijọba gbọdọ pese ‘sanwo-koo-too-lo’na’, iyẹn (prepaid meter) to pọ, to si ka gbogbo ile, o ni awọn o fẹẹ foju ri iwe owo ina alafojuda, eyi ti wọn n pe ni estimated bills, mọ. O ni oṣiṣẹ ina ẹlẹntiriiki to ba tun ha estimated bill fun araalu, awọn maa bẹrẹ si i fọlọpaa mu wọn ni, tori ole ati arẹnijẹ ni wọn.
Bi ọga NLC naa ṣe wi, iwọde ati ifẹhonuhan yii n waye nibi mẹrin ọtọọtọ nipinlẹ Eko: n’Ikẹja, Marina ati lawọn ileeṣẹ meji to n gbọ awuyewuye nipa ọrọ ina ẹlẹntiriiki, o si tun fidi ẹ mulẹ pe kari gbogbo ipinlẹ mẹrindinlogoji to wa ni Naijiria ati ilu Abuja lawọn ti ṣeto iwọde lọjọ Aje ọhun.