Faith Adebọla
Ojumọ kan, iṣẹlẹ kan, lọrọ awọn agbebọn ti wọn n ji awọn akẹkọọ gbe da bayii, pẹlu bi ọpọ akẹkọọ-binrin ileewe Federal College of Forestry Mechanisation, ṣe tun dawati loru mọju ọjọ Ẹti, Furaidee yii, nipinlẹ Kaduna. Awọn janduku agbebọn ni wọn lọọ ji wọn gbe ninu ọgba ileewe wọn, wọn si ti ko wọn wọ’gbo lọ.
Nnkan bii aago mẹta idaji ni wọn lawọn agbebọn naa ṣina ibọn bolẹ nileewe to wa nijọba ibilẹ Birnin Gwari ọhun, bẹẹ ileewe yii o jinna ju kilomita mẹẹẹdogun pere si ileewe ẹkọṣẹ ologun (Nigeria Defence Academy) to wa lagbegbe ọhun lọ.
Ọkunrin kan to n jẹ Abdullahi sọ fun Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa (NAN) pe: “Aago mẹta kọja iṣẹju mẹwaa la bẹrẹ si i gburoo ibọn, iro naa si rinlẹ gidi, o da bii pe niṣe ni wọn mọ-ọn-mọ fẹẹ fi ariwo ibọn naa bo igbe awọn akẹkọọ-binrin ti wọn fẹẹ ji ko naa mọlẹ, tori ko pẹ sigba ti wọn dawọ ibọn yinyin naa duro ni gbgbo agbegbe naa dakẹ wẹlo, ko si sẹni to gburoo bi wọn ṣe ko awọn ọmọleewe naa lọ.”
Ọkan lara awọn ọmọleewe to ṣẹku, Abiha Abubakar, sọ pe “Nnkan bii ọgbọn iṣẹju lawọn agbebọn naa fi n yinbọn leralera. Bi wọn ṣe n yinbọn naa lọwọ ni wọn ja wọ ile tawa akẹkọọ-binrin n sun, gbogbo wa niro ibọn ti ji kalẹ, inu ibẹrubojo la si wa. Bi wọn ṣe wọle ni wọn paṣẹ pe ki gbogbo wa jade. Awa kan ribi sa pamọ, a si fo fẹnsi ileewe wa ni o jẹ ki wọn ri wa mu.
“Wọn tun lọọ sile tawọn ọkunrin n gbe, ṣugbọn ọpọ awọn akẹkọọ-ọkunrin ni wọn ti fo fẹnsi ki wọn too de, adugbo Rigasa ati Mando ni wọn ba sa lọ, iwọnba awọn ọkunrin diẹ ni wọn ko lọ.”
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kaduna ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ. ASP Mohammed Jalige sọ pe awọn o ti i mọ pato iye akẹkọọ ti wọn ji gbe. O lawọn o le sọ boya ọkunrin wa laarin awọn ti wọn ji gbe, ṣugbọn awọn agbofinro ti n ṣiṣẹ lori iṣẹlẹ naa, awọn yoo si tete mọ bi awọn akẹkọọ naa yoo ṣe dominira laipẹ.
Bakan naa, kọmiṣanna fun eto aabo ati ọrọ abẹle nipinlẹ naa, Ọgbeni Samuel Aruwan, sọ pe loootọ niṣẹlẹ naa waye, ati pe iṣẹ iwadii ti n lọ lori ẹ. O lawọn ọlọpaa ti n ṣiṣẹ pẹlu awọn ṣọja lati mọ bi wọn ṣe maa doola ẹmi awọn majeṣin naa, o nijọba yoo sọrọ pato lori ẹ laipẹ.
Ṣa, awọn ṣọja lati ileewe awọn ologun ti lọọ ko awọn akẹkọọ to ṣẹku atawọn to raaye sa mọ awọn agbebọn naa lọwọ, wọn si ti ko gbogbo wọn lọ sinu ọgba ileewe ẹkọṣẹ ologun naa laaarọ ọjọ Ẹti, Furaidee. Ibẹ la gbọ pawọn akẹkọọ naa ṣi wa lọwọ yii.
Tẹ o ba gbagbe, oru mọju Ọjọbọ, Tọsidee, lawọn agbebọn kan lọọ ji awọn akẹkọọ ileewe ẹkọṣẹ ile kikọ ati imọ ẹrọ to wa ni Uromi, nipinlẹ Edo, gbe. Titi dasiko yii, wọn o ti i ri awọn akẹkọọ naa gba pada.