Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ọgbẹni Abiọdun Williams, ẹni to jẹ agbẹjọro fun Oludasilẹ ileetura Hilton, Dokita Ramon Adedoyin, ti ke sawọn ọlọpaa lati tuṣu desalẹ ikoko lori ẹni to sin oku akẹkọọ Fasiti Ifẹ, Timothy Adegoke, to ku si otẹẹli naa.
Iwadii fi han pe nigba ti awọn oṣiṣẹ otẹẹli naa ba oku Timothy ninu yara to gba ni wọn gbe oku rẹ ju sinu igbo kan loju-ọna Ifẹ/Ibadan, ṣugbọn ti wọn ko mọ ẹni to sinku rẹ ko too di pe awọn ọlọpaa lọọ hu u jade lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kọkanla, ti a wa yii.
Williams, ninu lẹta to kọ si kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu yii, ṣalaye pe iwadii oun fidi rẹ mulẹ pe awọn oṣiṣẹ eto ilera ti ijọba ibilẹ Aarin- Gbungbun Ifẹ (Department of Public Health, Ifẹ Central Local Government) ni wọn sin oku rẹ lẹyin ti wọn gba aṣẹ lọwọ awọn ọlọpaa niluu Ileefẹ.
Agbẹjọro yii rọ awọn ọlọpaa lati ṣewadii yii daadaa lati le mọ ipa ti awọn afurasi ti wọn ti mu pẹlu awọn oṣiṣẹ eto ilera naa ko ninu iku ati sisin oku Timothy, ki idajọ ododo si le fidi mulẹ.
O ni irọ pata ni pe awọn oṣiṣẹ ileetura Hilton ni wọn sin oku oloogbe naa, ṣe ni wọn ju u sinu igbo, to si jẹ pe awọn oṣiṣẹ ijọba ni wọn gbẹlẹ, ti wọn si sin oku rẹ.
O fi kun ọrọ rẹ pe ti awọn ọlọpaa ba le ri ọrọ yii fidi rẹ mulẹ, yoo ran awọn dokita ti wọn n ṣayẹwo si oku oloogbe lọwọ lati mọ ohun to ṣẹlẹ si oku rẹ ki wọn to sin in.