Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Lati bii osu kan sẹyin lọkan-o-jọkan awuyewuye ti n waye laarin ijọba ipinlẹ Ondo ati igbakeji gomina, Ọnọrebu Agboọla Ajayi, lori awọn ẹru ijọba kan ti wọn lo kọ lati ko silẹ lẹyin ti saa rẹ ti pari gẹgẹ bii igbakeji gomina lọjọ kẹtalelogun, osu keji, ọdun ta a wa yii.
Ọsẹ to kọja ni Dokita Doyin Ọdẹbọwale to jẹ Oludamọran fun gomina lori akanṣe iṣẹ si n fẹjọ Agboọla sun Kọmisanna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Bọlaji Salami, nínu iwe kan to kọ si i lorukọ Gomina Rotimi Akeredolu.
Adebọwale ni odidi ọkọ mẹrin, Toyota Land Crusher kan ati Hilux mẹta to jẹ tijọba lo si wa ni ikawọ ọkunrin naa lẹyin bii osu meji to ti kuro lori aleefa.
O ni ohun tí ko ni i ṣee ṣe ni ki wọn maa wo oludije ẹgbẹ oṣelu Zenith Labour Party ninu eto idibo gomina ọdun to kọja naa niran ko gbẹsẹ le ẹru awọn eeyan ipinlẹ Ondo lọna aitọ.
O ni ẹbẹ lawọn n bẹ ileeṣẹ ọlọpaa lati tete wa gbogbo ọna ti wọn yoo fi ba awọn gba gbogbo ẹru wọnyi pada lọwọ Agboọla ko too di pe ijọba kan an labuku ni gbangba.
Agboọla naa ko jẹ kọrọ ọhun tutu to fi sare fun Akeredolu lesi ninu atẹjade kan to fi sita nipasẹ akọwe iroyin rẹ, Allen Soworẹ.
Igbakeji gomina tẹlẹ ri ọhun ni ọkọ meji pere lo wa lọwọ oun, ki i ṣe mẹrin gẹgẹ bii ariwo ti wọn n pa.
O ni ọjọ kẹtalelogun, osu keji, ọdun 2021, ti saa oun pari loun ti gbe meji silẹ ninu ọkọ ijọba mẹrin to wa ni ikawọ oun.
Ọkọ meji yooku lo ni oun kọ lati gbe silẹ nitori pe ajẹmọnu oun ni wọn jẹ gẹgẹ bii ilana eto ijọba ipinlẹ Ondo.
Ori èyí ni wọn wa tawọn eeyan ipinlẹ Ondo si fọwọ lẹran ti wọn n woye iru itu ti Akeredolu fẹẹ fi alabaaṣiṣẹpọ rẹ tẹlẹ yii pa, nigba ti Agboọla tun fi atẹjade mi-in sita lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii pe oun yoo da awọn mọto naa pada.