Agoro, ọkunrin to ga ju lorilẹ-ede Naijiria ti ku o

Monisọla Saka

Afeez Agoro Ọladimiji, ọkunrin ti wọn gba pe oun lo ga ju nilẹ Naijiria, pẹlu ẹsẹ bata meje o le mẹrin, ti jade laye lẹni ọdun mejidinlaaadọta (48), lẹyin aisan ranpẹ.

Ọkunrin gigun gbọngbọnran, to tun maa n ṣere tiata ati eto lori ẹrọ tẹlifiṣan ọhun, ki aye pe o digbooṣe l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ karundinlogun, oṣu Kẹfa, ọdun yii, nile ẹ to wa lagbegbe Akọka, nipinlẹ Eko.

Lasiko tọkunrin naa sọ pe awọn ibi kan n dun oun ninu ara ni wọn sare gbe e digbadigba lọ sile iwosan, l’Ọjọruu, Wẹsidee, to si pada gbabẹ fi aye silẹ.

Igba ikẹyin tawọn eeyan ti gburoo ọkunrin yii lori ẹrọ ayelujara ni ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii, to kọ ọrọ idupẹ sori opo ayelujara Facebook rẹ lẹyin ti ara ẹ balẹ latari iṣẹ abẹ ibi egungun itan ẹ to ṣe. O ni iṣẹ abẹ naa yọri si rere, ati pe itọju niwọnba lo ku.

Ṣaaju igba naa ni ọkunrin yii ti rawọ ẹbẹ sawọn eeyan lati jọọ ran oun lọwọ lati ṣiṣẹ abẹ ibi egungun ìgbáròkó to n yọ ọ lẹnu.

Ninu ọrọ ẹ, Ọgbẹni Ṣẹgun Adesanya, ti i ṣe alaga adugbo Akọka ti oloogbe n gbe fidi iṣẹlẹ ipapoda rẹ mulẹ.

O ṣapejuwe rẹ bii ẹni to lọjọ iwaju daadaa, ṣugbọn ti iku da ẹmi rẹ legbodo.

O ni, “Agbegbe Community Road, ni Afeez Agoro n gbe, o si ba wa lọkan jẹ lati padanu ọkunrin to ni ọjọ iwaju to sunwọn bẹẹ. Ki Ọlọrun fun ẹmi rẹ nisinmi”.

Gbogbo awọn eeyan agbegbe Akọka ati Bariga, ni wọn n ṣedaro oloogbe. Bẹẹ lawọn eeyan lori ayelujara naa bara jẹ lori iku ọkunrin ọhun.

Wọn ni o ti pẹ ti ọkunrin naa ti n ke gbajare pe kawọn eeyan ran oun lọwọ lori ilera oun, ṣugbọn ti wọn ko ya si i, titi to fi faye silẹ.

Leave a Reply