Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Minisita fun ọrọ abẹle lorileede yii, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla, ti sọ pe iṣẹ ọwọ awọn aturọta bii elubọ ati arijẹnidii-mọdaru ni ahesọ kan to n lọ kaakiri pe oun n tabuku oludije funpo aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu APC, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu.
Ninu atẹjade kan ti Oludamọran rẹ lori eto iroyin rẹ, Ṣọla Faṣure, fi ṣọwọ si Alaroye lo ti ṣapejuwe iroyin to n ja ran-in-ran-in kaakiri ori ikanni ayelujara naa gẹgẹ bii irọ to jinna sootọ.
O ni erongba awọn mọdaru naa ni lati ri i pe gbogbo ilakaka awọn eeyan rere ninu ẹgbẹ naa lati yanju gbogbo aawọ to wa nilẹ ṣaaju idibo aarẹ oṣu to n bọ ja si pabo.
Atẹjade naa fi kun un pe bi awọn aṣaaju inu ẹgbẹ naa ṣe n gbiyanju lati ri i pe ekuru ọrọ ọhun tan lawo naa ni awọn kọlọransi yii n gbọnwọ rẹ sawo, ti wọn si n gbin irugbin iyapa sinu ẹgbẹ naa.
O waa ke si awọn eeyan orileede Naijiria lati ṣọrọ fun awọn irinṣẹ eṣu yii nitori afojusun wọn ni lati da wahala silẹ ninu ẹgbẹ APC.
O ni ohun kan ṣoṣo to jẹ Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla logun bayii ni mimu atunṣe nla ba ileeṣẹ ọrọ abẹle lorileede yii labẹ idari Aarẹ Muhammadu Buhari, ati lati ri i pe ẹgbẹ APC jawe olubori ninu idibo apapọ ọdun yii.