Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ni nnkan bii aago meji oru Ọjọbọ, ọjọ kẹrin, oṣu kẹsan-an yii, lasiko ti kaluku n sun lọwọ ni ọdọmọkunrin kan, Ahmed Elegbede, n fọ ṣọọbu oniṣọọbu laduugbo Powerline, Gbọkọniyi, l’Abẹokuta. O ti ji awọn nnkan jijẹ to fẹẹ ji, o si ti kuro nibẹ, asiko to n ti oko ole naa bọ lo bọ sọwọ awọn fijilante lagbegbe Adigbẹ, n ni wọn ba mu un pẹlu awọn ẹru to ji naa.
Awọn nnkan jijẹ bii Indomie to wa ninu paali ateyi to wa ninu ọra ni Ahmed ko ni ṣọọbu naa, bẹẹ lo gbe irẹsi ti wọn di sinu apo atawọn ọra ti wọn fi n di nnkan. Ko ṣalai gbe gaasi idana ti ẹni to ni ṣọọbu naa n lo, o jọ pe kinni naa lo fẹẹ maa fi se awọn ounjẹ to ji ko ọhun.
Ṣugbọn nigba to de Adigbẹ loru, lasiko to n dari lọ sile, niṣẹ lo bọ sọwọ awọn fijilante ẹka VGN to n ṣọ agbegbe yii, bi wọn ṣe mu un ṣinkun niyẹn.
Nigba to n ṣalaye ara ẹ fawọn fijilante naa, Ahmed sọ pe babalawo loun. O loun lọọ ṣiṣẹ oru fawọn onibaara ti wọn n ṣe aajo lọwọ oun ni. Ṣugbọn nigba ti wọn tu ẹru rẹ, ti wọn ba awọn paali Indomie ati apo irẹsi pẹlu gaasi idana, ti ko si le ṣalaye iru ẹbọ to n fi iru nnkan bẹẹ ru ni aṣiri tu. Ọmọdekunrin to ni babalawo loun naa si jẹwọ pe oun lọọ fọ ṣọọbu oniṣọọbu ni Gbọkọniyi ni.
Ibi ti wọn ti mu un naa ko jinna si teṣan ọlọpaa, ẹsẹkẹsẹ naa ni wọn si mu un wọbẹ, ti wọn fa a le awọn ọlọpaa lọwọ. Ọsẹ yii ni ireti wa pe oun naa yoo de kootu, nibi ti yoo ti ṣalaye ara ẹ fun adajọ, ti yoo si gba idajọ to ba tọ si i.