Adewale Adeoye
Gomina ipinlẹ Ṣokoto tẹlẹ, to tun jẹ olori ile igbimọ aṣoju-ṣofin tẹlẹ, Sẹnetọ Aminu Waziri Tambuwal, ti ni pe aigbọran ọpọ awọn araalu ti wọn dibo fẹgbẹ oṣelu APC lasiko eto idibo ọdun 2023 to kọja yii lo ko awọn ọmọ orileede Naijiria sinu ipọnju ati iya ajẹkudorogbo ta a wa bayii.
Sẹneto Tambuwa sọrọ ọhun di mimọ lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ keji, oṣu Kẹfa, ọdun yii, nibi eto pataki kan to waye laarin awọn oloye ẹgbẹ oṣelu PDP kan nipinlẹ Ṣokoto.
O ni, ‘’Bẹ kẹ ẹ si maa wo o, lasiko ta a n ṣepolongo ibo lọdun to kọja yii, a ṣekilọ gidi fawọn araalu, paapaa ju lọ awọn mẹkunu pe ki wọn ma dibo wọn fun ẹgbẹ APC rara, nitori a ti mọ daju pe wọn ko lohun gidi kankan ti wọn fẹẹ ṣe faraalu rara.
‘‘A mọ daadaa pe wọn ko si ni igbaradi kankan lati ṣakoso ijọba orileede yii rara, wọn ko ni afojusun gidi kan, wọn ko leto gidi kankan lọwọ, agbara kan n wu wọn lati ja gba ni, wọn ti ja agbara ati ipo naa gba lọwọ awọn ẹni to kunju oṣuwọn bayii, ṣugbọn wọn ko mọ ohun ti wọn le ṣe si i lati ṣatunṣe sijọba orileede yii mọ’’.
Sẹnetọ Tambuwal waa rọ awọn araalu gbogbo pe ki wọn fọwọ-sowọ-pọ pẹlu awọn lati le ijọba APC kuro lori oye, ki awọn ẹni to kunju oṣuwọn lati ṣejọba le gbajọba lọwọ wọn lọdun 2027.
O ni, ‘Ojuṣe gbogbo wa pata ni lati wa ni iṣọkan bayii, ka le ṣiṣẹ pọ lati gbajọba orileede yii lọwọ APC ti wọn n ṣe e baṣu-baṣu lọwọlọwọ yii.