Aisan jẹjẹrẹ pa ọmọ olori ileegbimọ aṣofin tẹlẹ

Inu ọfọ nla ni olori ileegbimọ aṣofin agba tẹlẹ, David Mark atawọn mọlẹbi rẹ, wa bayii. Eyi ko sẹyin ti iku aitọjọ to mu akọbi rẹ lọkunrin, Tunde Mark, lọ lai ro tẹlẹ. Aisan jẹjẹrẹ la gbọ pe o kọ lu ọmọkunrin ẹni ọdun mọkanlelaaadọta naa, to si mu ẹmi re lọ.

Ileewosan kan niluu London, lorileede UK, la gbọ pe Tunde dakẹ si laaarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, opin ọsẹ yii, gẹgẹ bi Paul Mumeh to jẹ oludamọran pataki fun baba oloogbe ṣe wi ninu atẹjade kan to fi sita.

O ni ọmọkunrin naa dakẹ laaarọ ọjọ Ẹti, ọpọ awọn mọlẹbi, ojulumọ atawọn ololufẹ rẹ lo yi i ka lasiko to fẹẹ mi imi ikẹyin yii.

Mumeh ni ọjọ kẹtala, oṣu Kẹwaa, ọdun 1971, ni wọn bi i. Ileewe alakọọbẹrẹ tawọn ologun to wa ni Yaba, niluu Eko, iyẹn Yaba Military College, lo ti kawe alakọọbẹrẹ. Lẹyin eyi lo lọ sileewe girama ti wọn pe ni Bradfield College, Berkshire, niluu London.

Bẹẹ lo tun gba oye imọ ijinlẹ sayensi ni Yunifasiti Kings College, ni London kan naa. O tun kawe ni ileewe giga Harvard, Cambridge, ni Massachutess, lati fi imọ kun imọ.

Iyawo ati ọmọbinrin kan la gbọ pe oloogbe naa fi saye lọ.

Leave a Reply