Ọkan ninu awọn gbajumọ oṣere tiata ilẹ wa to ku lojiji, Racheal Oniga ti sọ pe kawọn eeyan ma wa iku to pa obinrin yii lọ sọdọ Korona gẹgẹ bi awọn kan ṣe n gbe e kiri, wọn ni aisan ọkan niku yii tọ wa.
Deaconess Toyin Oduṣọtẹ, to jẹ mọlẹbi oloogbe naa lo sọ eyi di mimọ ninu atẹjade kan to buwọ lu lorukọ mọlẹbi wọn lọjọ Abamẹta, Satide yii. Atẹjade ọhun ṣalaye pe ọkan Racheal lo daṣẹ silẹ lojiji, lọganjọ oru ọjọ Ẹti, Furaidee, mọju Satide, tobinrin naa fi dagbere faye.
O ni o ti ṣe diẹ sẹyin ti irawọ oṣere tiata naa ti n ba aisan ọkan finra, bo tilẹ jẹ pe kinni naa ko kuku rẹn ẹn mọlẹ, ko si da a dubulẹ rara.
Atẹjade naa, ti akọle rẹ ka pe “Atẹjade gidi lori iku Olooye Racheal Tabuno Oniga,” ṣalaye pe:
“Pẹlu ẹdun ọkan gidi, ti a si gba fun ifẹ-inu Ọlọrun, a kede ipapoda arabinrin wa, olufẹ, iya wa, ati iya agba wa, Oloye Racheal Tabuno Oniga. O ku ni deede aago mẹwaa alẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọgbọnjọ oṣu keje, ọdun 2021 yii, sileewosan kan nipinlẹ Eko, lẹni ọdun mẹrinlelọgọta.
A fi akoko yii sọ fẹyin eeyan pe ọkan rẹ lo daṣẹ silẹ lojiji, aisan ọkan naa ko si ṣẹṣẹ bẹrẹ, o ti n ba a yi fungba diẹ sẹyin kọlọjọ too de yii.”