Oluṣẹyẹ Iyiade
Oludasilẹ ijọ INRI Evangelist Spiritual Church lorilẹ-ede yii, Primate Elijah Ayọdele, ti fero ọkan rẹ han lori aisan to n ba Gomina ipinlẹ Ondo, Arakunrin Rotimi Akeredolu, finra lọwọ.
Agba ojisẹ Ọlọrun ọhun sọ ninu atẹjade to fi sita nipasẹ akọwe iroyin rẹ, Ọgbẹni Oluwatoyin Ọshọ, pe afi kawọn ololufẹ Aketi gbadura fun un daadaa, nitori ohun to fara han gbangba ni pe aisan to n ṣe e ki i ṣoju lasan, awọn eeyan kan lo wa nidii rẹ ko ma baa lanfaani ati tẹsiwaju ninu iṣẹ ilu to n ṣe lọwọ.
Ayọdele ni oun gba awọn ẹbi Arakunrin nimọran ki wọn jawọ ninu bi wọn ṣe n gbe e lati ọsibitu kan si omiiran, ki wọn si bẹrẹ si i fẹsẹ ile tọ ọrọ ailera rẹ, ṣe oju bọrọ ko ṣee gb’ọmọ lọwọ ekurọ.
O ni ṣe lo yẹ kawọn ẹbi Gomina Akeredolu tubọ maa woju Ọlọrun nitori adura nikan lo nilo lọwọ ta a wa yii, ko le pada wa si ọfiisi rẹ layọ ati alaafia
O waa rọ awọn ti wọn fẹran Aketi daadaa ki wọn maa gbadura fun un kikankikan, ki wọn ma si ṣe gba awọn oloṣelu laaye lati ki oṣelu bọ ailera rẹ fun imọtara tiwọn nikan.