Aisha Buhari mu iyawo Tinubu yika inu Aso Rock

Adewale Adeoye
Ni imurasilẹ lati gbọpa aṣẹ gẹgẹ bii iyawo olori orile-ede yii, iyawo Aarẹ ilẹ wa, Aisha Buhari, ti mu iyawo aarẹ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, Sẹnetọ Olurẹmi Tinubu, yika inu agbala ile ìjọba ti wọn n pe ni Aso Rock. lbi yii ni aarẹ tuntun pẹlu iyawo rẹ yoo maa gbe ni gbara ti wọn ba ti gbe ọpa aṣẹ le wọn lọwọ lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii.
Ninu fidio kan to n ja ran-in lori ayelujara nipa igbesẹ ohun, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu Karun-un, ọdun yii, ni Aisha Buhari ṣafihan pataki ọhun fun iyawo Tinubu.
Ninu fidio naa ni Aisha Buhari ti mu Olurẹmi wọle, to si ṣalaye fun un pe awọn ti ko gbogbo ẹru awọn kuro ninu ileejọba, oun ati ọkọ oun ti wa nibi ti wọn n pe ni ile oni gilaasi, iyẹn Glass House. O ni ile yii ni awọn ti wọn ba fẹẹ kuro nileejọba yoo maa duro si.
O waa gba iyawo aarẹ tuntun to fẹẹ wọle naa nimọran pe ki wọn ri i bii aṣa pe ile gilaasi yii ni aarẹ to ba n lọ yoo maa wa titi ti ọjọ ti wọn yoo kuro nilee jọba yoo fi pe.
Aisha ṣafihan awọn ibi kọọkan to ṣe pataki ninu Aso Rock ọhun fun un, ko baa le mọ ibi to maa rin si nigba to ba ti wọlẹ gẹgẹ bii iyawo aarẹ tuntun.
Nigba to n sọrọ lori abẹwo naa, Olurẹmi Tinubu ni abẹwo naa je eyi to mu inu oun dun. O ni bo tilẹ jẹ pe akoko kekere naa lawọn fi yi ile ohun po, o jẹ ohun iwuri foun, oun yoo si tete mọ awọn ohun to yẹ ni ṣiṣe ti oun ba wọle agbara naa, pẹlu iranlọwọ Ọlọrun, awọn yoo mu ayipada to nipa rere ba orile-ede yii.

Leave a Reply