Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọkunrin ọmọ ọdun mẹtalelogun kan, Dominic David, lo ti n kawọ pọnyin rojọ lọwọ nile-ẹjọ Majisireeti to wa lagbegbe NEPA, l’Akurẹ, latari ẹsun ṣiṣe ọmọdebinrin ẹni ọdun marun-un kan basubasu ninu ile to n gbe niluu Idanre.
Ọmọbinrin ọhun ta a forukọ bo laṣiiri ọhun la gbọ pe Dominic fi bisikiiti tan lọ sile rẹ to wa lagbegbe Basic Road, Odode-Idanre, lọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2023 ta a wa yii, nibi to ti ṣe ọmọ naa ni iṣekuṣe, lẹyin eyi ni wọn lo tun kilọ fun ọmọdebinrin naa lati pa ẹnu rẹ mọ, o ni ko gbọdọ sọ ohun ti oun foju rẹ ri fawọn obi rẹ ti ko ba fẹẹ kan idin ninu iyọ.
Ọmọ ta a n sọrọ rẹ yii ko kọkọ fẹẹ sọrọ loootọ nigba to dele wọn latari ikilọ ti ọkunrin agbaaya yii ti fun un, ṣugbọn nigba to di pe oju abẹ bẹrẹ si i ro o, ti ko si gbadun ara rẹ mọ, lo ṣẹṣẹ waa jẹwọ itu ti Dominic fi i pa fun iya rẹ.
O ni Buọda Dominic lo fi bisikiiti tan oun lọ sinu yara kan to n gbe nibi to ti funra rẹ bọ pata nídìí oun, ko too bẹrẹ si i fi ika ọwọ rẹ dabira soju ara oun.
Iya ọmọdebinrin naa ko fi ọrọ ọhun falẹ rara pẹlu bo ṣe mori le teṣan ọlọpaa ilu Idanre lati lọọ fẹjọ ọkunrin oni kinni ko mọ ọmọde ọhun sun, kiakia lawọn ọlọpaa si ti fi pampẹ ofin gbe e, ti wọn si tete fi ṣọwọ si ẹka to n ṣe iwadii iwa ọdaran ni olu ileesẹ wọn to wa l’Akurẹ.
Lẹyin ti wọn ti ṣe ọkan-o-jọkan ifọrọwanilẹnuwo fun un tan ni wọn taari rẹ sile-ẹjọ lati lọọ koju ẹsun ṣiṣe ọmọde basubasu ti wọn fi kan an.
Ninu ọrọ Martins Olowofẹsọ to jẹ agbefọba, o ni aisi kiriimu ni olujẹjọ ọhun kọkọ fi pa oju ara ọmọbinrin naa ko too bẹrẹ si i fi ika rẹ ro o.
Olowofẹsọ ni Dominic ti kọkọ ṣe ohun kan naa si ẹgbọn ọmọbìnrin yìí to to bii ọmọ ọdun mẹwaa lọdun to kọja, ti ẹni to jẹ baba wọn, iyẹn Ọgbẹni Olufẹmi, si mu ẹjọ rẹ lọ si teṣan nigba naa.
O ni ọmọkùnrin ọhun tọwọ bọwe adehun ni teṣan, to si ṣeleri pe oun ko tun ni i dan iru rẹ wo mọ, ṣugbọn to kuna ati mu adehun rẹ ṣẹ pẹlu bo tun ṣe lọọ ṣe ohun kan naa fun aburo ọmọ yii.
Agbefọba ni ko si ani-ani pe olujẹjọ ti ṣẹ si abala kẹrin, ila kin-in-ni ati ekeji ninu iwe ofin ipinlẹ Ondo ti ọdun 2021, eyi to n daabo bo ẹtọ awọn ọmọde.
O ni ko yẹ ki ọmọkunrin naa wa lawujọ eeyan latari iwa rẹ, o ni ki adajọ paṣẹ pe ki wọn lọọ fi i pamọ sinu ọgba ẹwọn titi di ọjọ mi-in ọjọ ire, nitori awọn iwa ati iṣe buruku to wa lọwọ rẹ.
Bakan naa lo tun bẹbẹ fun sisun igbẹjọ siwaju ko le ni oore-ọfẹ ati ṣe awọn eto to yẹ fun itẹsiwaju igbẹjọ.
Agbẹjọro olujẹjọ, Amofin O. Ọlawale ninu ọrọ tirẹ bẹbẹ fun gbigba beeli onibaara rẹ, o ni olujẹjọ naa si jẹ alaimọkan labẹ ofin titi ti adajọ yoo fi gbe idajọ rẹ kalẹ.
Nigba to n gbe ipinnu rẹ kalẹ, Onidaajọ Fọlaṣade Aduroja gba ẹbẹ agbefọba wọle pẹlu bo ṣe ni ki wọn maa gbe ọkunrin naa lọ sinu ọgba ẹwọn na.
Ọjọ kẹsan-an, oṣu Keji, ọdun yii ni adajọ ni igbẹjọ yoo tun maa tẹsiwaju.