Ajakalẹ arun wọle si fasiti yii, akẹkọọ mẹtala ti ku lojiji

Jamiu Abayọmi

Inu ibẹrubojo ati ijaya nla ni gbogbo awọn akẹkọọ ile-iwe Enugu State University of Science and Technology (ESUT), to wa ni Agbani, nipinlẹ Ẹnugu, wa bayii, latari bi ajakalẹ arun kan ti ẹnikan ko mọdi ṣe wọle tọ wọn ti akẹkọọ mẹtala si ti padanu ẹmi wọn laaarin ọsẹ meji pere sira wọn.

ALAROYE gbọ pe iṣẹlẹ ọhun ti gba ẹmi awọn akẹkọọ ti wọn waa kawe lati le jẹ ki ọjọ ọla wọn dara, ṣugbọn ti wọn n gbabẹ dero ọrun aremabọ. Koda, di Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu yii, ko din ni akẹkọọ mẹtala ti arun ọhun ti sọ di ero ọrun ọsan-gangan. Iṣẹlẹ yii ti ko ipaya nla ba awọn akẹkọọ, olukọ, ati gbogbo awọn oṣiṣẹ inu ọgba naa pe ṣe ko ni ran awọn ni irinajo ti awọn ko mura rẹ bayii.

Lara awọn akẹkọọ ti wọn ba oniroyin sọrọ lori iṣẹlẹ naa fidi ẹ mulẹ pe, “bi awọn ẹgbẹ wa ba ti dubulẹ aisan ti a si gbe wọn lọ sileewosan, ibẹ ni wọn n gba dero ọrun lai pada wale mọ, o si n kọ awọn alaṣẹ ile-iwe naa lominu.

“A o mọ boya arun to n tinu afẹfẹ wa ni tabi tinu omi, idi niyi ti ijọba ipinlẹ yii, paapaa ẹka eto ilera ati awọn alaṣẹ ile- iwe, ṣe gbọdọ wa nnkan ṣe si i ko too di ajakalẹ arun nla”.

Eyi lo jẹ ki ẹgbẹ awọn akẹkọọ, National Association of Nigerian Students (NANS), ẹka ti Guusu Ila-Oorun orileede yii ke si ijọba atawọn alaṣẹ ile-iwe naa lati ti il pa fungba diẹ na, eyi ti yoo le fun wọn laaye lati ṣewadii ohun to fa iṣẹlẹ naa, ki wọn si wa ọna abayọ si i.

Ninu atẹjade kan ti wọn fi lede l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹjọ, lẹgbẹ ede ti wọn pe akori rẹ ni ipe fun titi ile-iwe (ESUT) pa ni kiakia.

Ẹgbẹ naa lawọn ko ni laju awọn silẹ ki awọn akẹkọọ maa ku pipiiipi, leyii tawọn alaṣẹ si kọ lati wa ojuutu ati ọna abayọ si ajalu aburu  naa.

“A n fẹ ki ile-iwe naa wa ni titi pa titi ti wọn aa fi wa ọna abayọ si arun naa, ki a si le raaye ṣe ipade pẹlu awọn ajọ eleto ilera ati awọn aṣoju ileewe naa.

“A n fẹ ki awọn akẹkọọ pada sile awọn obi wọn, nibi ti nnkan kan ko ti ni i di alaafia wọn lọwọ, a si gbadura pe ki Ọlọrun fi ọrun kẹ gbogbo awọn to ti doloogbe”.

Agbẹnusọ ile iwe naa, Ikechukwu Ezianioma, ni irọ ati abumọ lo pọ ninu nnkan ti awọn akẹkọọ yii sọ, nitori awọn alaṣẹ ti gbe ọpọlọpọ igbesẹ lati wadii arun naa, koda kọmiṣanna fun eto ilera ti mọ si i, wọn si ti bẹrẹ iṣẹ lori bi wọn yoo ṣe pana iṣelẹ ọhun.

 

Leave a Reply