Ajalu buruku leleyii o! Ọba alaye mẹta waja lọjọ kan naa nipinlẹ Ọyọ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Gbogbo agbegbe Ogbomọṣọ, nipinlẹ Ọyọ, lo wa ninu ọfọ bayii pẹlu bi ọba alade mẹta ṣe waja laarin iṣẹju kan ṣoṣo lọjọ kan naa.

Awọn ọba ọhun, ti awọn mẹtẹẹta jọba si ilu kaluku wọn, nijọba ibilẹ Oriire, lagbegbe Ogbomọṣọ, nipinlẹ Ọyọ, ni wọn padanu ẹmi wọn sinu ijamba ọkọ to waye labule kan ti wọn n pe ni Arinkinkin, nitosi ilu Ogbomọṣọ, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ keji, oṣu Kejila, ọdun 2023 yii.

Ọlọọlọ ti Ọọlọ, Ọba Oyebunmi Ajayi, to jẹ ọkan ninu awọn ọba agbegbe Ogbomọṣọ, lo n ṣayẹyẹ oku mọlẹbi ẹ kan nigboro ilu Ọpọlọ, nitosi Ogbomọṣọ níbẹ.

Ibi ayẹyẹ oku yii lawọn ọba naa n lọ lati yẹ akẹgbẹ wọn si ti ijamba mọto ọhun fi waye.

Wọn ni niṣe ni mọto ayọkẹlẹ to gbe awọn ori-ade wọnyi ko sabẹ ọkọ tirela kan to n bọ niwaju, ti awọn kabiesi mẹtẹẹta to wa ninu ọkọ ayọkẹlẹ ọhun si j’Ọlọrun nipe loju-ẹsẹ, nigba ti dẹrẹba to wa wọn fara pa yanna-yanna.

Awọn ọba to padanu ẹmi wọn sinu ijamba ọhun ni Olodogbo ti Odogbo, Onibowula ti Bowula, ati Alayetoro tilu Ayetoro, ti gbogbo wọn wa nijọba ibilẹ Oriire, nipinlẹ Ọyọ.

ALAROYE gbọ pe ileewosan olukọni to wa niluu Ogbomọṣọ, iyẹn Ladoke Akintọla University of Technology Teaching Hospital, ni wọn sare gbe awọn ọba naa lọ, ti wọn si pada tọju oku wọn pamọ si yara ti wọn n ṣe oku lọjọ si nileewosan naa lẹyin ti iwadii awọn dokita ti fidi ẹ mulẹ pe wọn ti dagbere faye.

Leave a Reply