Ajalu buruku leleyii o! Olukọ Fasiti Ifẹ ṣubu lulẹ ninu ọfiisi, lo ba ku

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Agbọ-sọgba-nu ni iku ọkan lara awọn olukọ agba ni ẹka imọ ẹkọ, Faculty of Education, ni Fasiti Ifẹ, Dokita Ayọdeji Obisẹsan Ọjẹdiran, to deede ṣubu lulẹ, so si ṣe bẹẹ jade laye jade.

ALAROYE gbọ pe laaarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrinla, oṣu yii, ni dokita naa ṣubu lulẹ ninu ọfiisi rẹ, to si ku.

Alukoro Fasiti Ifẹ, Abiọdun Ọlarewaju, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni loootọ niṣẹlẹ naa waye, ibanujẹ nla lo si jẹ fun gbogbo awọn alaṣẹ atawọn ọmọọleewe naa.

Latigba ti ọkunrin yii ti ku ni awọn akẹkọọ ti wọn ti gba ọdọ rẹ kọja ri ti n ṣọfọ rẹ lori ikanni ayelujara, ti wọn si n royin oloogbe naa  gẹgẹ bii olukọ to nifẹẹ, to laaanu to si niwa tutu bii adaba.

Ọkan lara iru rẹ ni eyi ti Ajiferukẹ Temilọla sọ, o ni nigba ti oun wa ni ipele keji (200L), loun salaabapade Dokita Ọjẹdiran, o si jẹ olukọ ti ko lafijọ.

O ni aimọye akẹkọọ ni ọkunrin naa n sanwo ileewe wọn ninu ọgba Fasiti Ifẹ, bẹẹ ni ko si iranlowọ ti ẹnikẹni wa lọ sọdọ rẹ ti ko ni i fi tọkantọkan ṣe e.

Temilọla fi kun ọrọ rẹ pe oun kan ṣoṣo to maa n dun mọ ọkunrin yii ninu ni ki awọn akẹkọọ maa tẹ siwaju lẹnu ẹkọ wọn, ko si si akẹkọọ ti ko fẹran rẹ.

Leave a Reply