Theo-Ọmọlohun, Oke-Ogun
Agbọ-sọgba-nu ni iku ọkunrin oloṣelu kan, Jacob Funmi Ogunmọla, to jẹ ọmọ ẹgbẹ Accord, ti wọn si ti dibo abẹlẹ yan lati ṣọju ẹgbẹ naa nileegbimọ aṣoju-ṣofin ninu eto idibo ti yoo waye lọdun to n bọ, ṣugbọn to ku lojiji lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrin, oṣu Kejila yii, ṣi n jẹ fun gbogbo awọn alatilẹyin rẹ titi di ba a ṣe n sọ yii.
ALAROYE gbọ pe laaarọ kutukutu ọjọ Aiku naa lọkunrin yii ti kọkọ sọ fun awọn eeyan kan to sun mọ ọn pe aya n dun oun, ti wọn si gba a nimọran pe ko wa nnkan lo.
Wọn ni Ogunmọla tun ṣepade pẹlu awọn ẹṣọ Amọtẹkun ti wọn feẹ ba a lọ sibi ipolongo ibo rẹ to fẹẹ lọọ ṣe niluu Ṣẹpẹtẹri laaarọ ọjọ Aiku ọhun, leyii to fi han pe ki i ṣe aisan kan to da a gbalẹ lo n ṣe e.
Ọkunrin naa wa nibi to ti n ṣe ipolongo ibo fawọn eeyan ilu Ṣẹpetẹri, nitosi Ṣaki, to si polongo ibo kikan kikan pe ki awọn eeyan ilu naa dibo fun oun pẹlu ọkan-o-jọkan ileri igbe aye irọrun to ṣe fun wọn. Nitori oun lo fẹẹ ṣoju awọn eeyan agbegbe Atisbo/Ila Oorun ati Iwọ Oorun Ṣaki nileegbimọ aṣoju-ṣofin niluu Abuja lorukọ ẹgbẹ oṣelu Accord.
ALAROYE gbọ pe nibi ipolongo yii lo ti fura pe nnkan kan n ṣe oun lagọọ ara, ara ko rọ ọ mọ. N ni ọkunrin ọmọ bibi ilu Agọ-Arẹ yii ba fi ori pepele ti wọn ti n polongo ibo silẹ, o ni ki awọn eeyan naa fun oun laaye ki oun yẹju kuro nibẹ fun iṣẹju diẹ, oun n pada bọ. Ṣugbọn alọ rẹ ni wọn ri, wọn ko ri abọ rẹ. Nigba ti wọn yoo si fi gburoo rẹ, ọkunrin naa ti dagbere faye.
Inu mọto re la gbọ pe o lọ, wọn kọkọ fẹẹ gbe e lọ si ọsibitu kan niluu naa, nigba to ya ni wọn ba tun ni ki wọn kuku maa gbe e lọ si ọdọ dokita rẹ niluu Eko. Inu ọkọ naa ni wọn ni nnkan ti yiwọ, ti ọkunrin naa ko si mọ ibi to wa mọ. Nigba ti oloju yoo si fi ṣẹ ẹ, ọkunrin oloṣelu ti wọn ni o maa n fowo rẹ ṣaanu, to si maa n ran awọn eeyan agbegbe rẹ lọwọ naa ko de Eko to fi ku.
Ọmọ bibi ilu Agọ-Arẹ, nipinlẹ Ọyọ, naa ti figba kan dipo alaga ijọba ibile Atisbo mu. Lẹyin eyi ni ẹgbẹ Accord si dibo yan an lasiko idibo abẹlẹ wọn lati ṣoju awọn eeyan agbegbe Atisbo/Ila Ooorun ati Iwọ Oorun Ṣaki nileegbimọ aṣoju-ṣofin lasiko eto idibo to n bọ.
Ẹni aadọta ọdun ni wọn pe Jacob Funmi Ogunmọla.