Ajibọla yoo lo ọdun mẹwaa lẹwọn, ọmọ ọdun mejila lo fipa ba lo pọ l’Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ile-ẹjọ giga kan nipinlẹ Ekiti ti paṣẹ pe ki ọkunrin ọlọkada ẹni ogoji ọdun kan, Ọgbẹni Ọdẹbọ Ajibọla, maa lọọ gbatẹgun lọgba ẹwọn fun ọdun mẹwaa gbako.

Ajibọla to jẹ gbajugbaja ọlọkada l’Ado-Ekiti, ni awọn ọlọpaa gbe wa siwaju Adajọ Bamidele Ọmọtọshọ, lọdun 2021, pẹlu ẹsun kan to ni i ṣe pẹlu ifipabanilopọ.

Gẹgẹ bi iwe ẹsun ti wọn fi kan ọdaran yii ni ọjọ kọkanlelọgbọn, ninu oṣun Kin-in-ni, ọdun 2021 se sọ, wọn ni o fipa ba ọmọdebinrin ẹni ọdun mejila lo pọ, ẹsun yii ni wọn juwe pe o lodi sofin ifipabanilopọ tipinlẹ Ekiti n lo, ti ọdun 2012.

Ninu iwe ẹsun  ti awọn ọlọpaa fi gba oun ọmọdebinrin naa silẹ nigba ti iwadii n lọ lọwọ ni tesan wọn, o ṣalaye pe lọjọ ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ, oun lọọ wo ọrẹ oun kan ni adugbo Ojumoṣe, ni Ado-Ekiti, o ni nigba ti oun n pada bọ nile, ti ilẹ ti ṣun ni oun ri ọkunrin kan to jẹ ọrẹ baba oun, o beere idi ti oun ṣe n fi ẹsẹ rin nigba ti ilẹ ti ṣun.

O ni ọrẹ baba oun yii lo fun oun lowo, to si da ọdaran ọlọkada yii duro, to si fun un ni igba Naira pe ko gbe oun dele. Ọmọbinrin yii ni kaka ki ọlọkada yii gbe oun lọ sile, niṣe lo gbe oun lọ si ibomiiran ti oun ko mọ, ọjọ keji loun ṣẹṣẹ mọ pe adugbo Okutagbokutalori ni oun wa.

O sọ pe niṣe ni oun sadeede ba ara oun ninu yara kan, ṣugbọn ọkunrin ọlọkada yii ko si ninu yara naa pẹlu oun lọjọ to gbe oun de adugbo naa. O ni nigba to di ọjọ keji lo wa, to si fipa ba oun lo pọ.

Nigba to n fi idi ẹjọ tirẹ mulẹ, Agbefọba ile-ẹjọ naa, Ọgbẹni Kunle-Shina Adeyẹmọ, pe ẹlẹrii marun-un, o si ko iwe ti wọn fi gba oun lẹnu ọdaran naa silẹ gẹgẹ bii ẹsibiiti.

Ọdaran naa to sọrọ lorukọ agbẹjọro rẹ, Emmanueli Adetifa, sọ pe loootọ ni wọn sọ pe ki onibaara oun gbe ọmọdebinrin naa lọ si ile, ṣugbọn to sọ fun un pe oun ko fẹẹ lọ sile lọjọ naa.

O fi kun un pe idi niyi ti oun fi gbe e lọ si ile ẹgbọn oun, o ni nigba ti oun fẹẹ ba a lo pọ, oun ri i pe wọn ko ti i ja ibale rẹ, idi niyi ti oun ṣe fi silẹ. Lẹyin eyi lo pe ẹlẹrii meji.

Ninu idajọ rẹ, Onidaajọ Bamidele Ọmọtọshọ, sọ pe oun ri ẹsun ifipabanilopọ ninu ẹsun ti wọn fi kan ọdaran naa. O ṣalaye pe ẹsun ifipabanilopọ ti wọpọ ju laarin awọn ọdọ iwoyi.

Adajọ ni ti oun ba fun ọdaran naa laaye lati san owo itanran, ko ni kọ ẹlomiiran to ba ṣe iru ẹsẹ bẹẹ lọgbọn. O ṣalaye siwaju si i pe ile-ẹjọ naa yoo fi oju aanu wo ọdaran yii nitori pe ko ṣẹ iru ẹṣẹ bẹẹ ri, ati pe oun gan-an lo jẹ opomulero ninu mọlẹbi rẹ, gẹgẹ bi agbẹjọro rẹ ṣe sọ.

O sọ pe, “Ile-ẹjọ yii sọ iwọ Ọgbẹni Ajibọla si ẹwọn ọdun mẹwaa gbako pẹlu iṣẹ aṣekara. Ọdun mẹwaa naa yoo bẹrẹ lati ọdun 2021 to ti wa lọgba ẹwọn naa”.

 

Leave a Reply