Ajinigbe ju iyawo pasitọ ti wọn ji gbe silẹ, wọn tun ji ẹni to gbowo waa fun wọn

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

A ko le sọ pe inu idunu ati ayọ lawọn ẹbi Pasitọ ijọ Ridiimu ‘ The Redeemed Christian Church Of God (RCCG), kan, Pasitọ Johnson Ajiboye, tawọn ajinigbe ji iyawo rẹ gbe sa lọ ni nnkan bii ọsẹ meloo kan sẹyin wa bayii. Bo tilẹ jẹ pe wọn ti ju Abilekọ Bọla Ajiboye ti i ṣe iyawo pasitọ naa silẹ, ṣugbọn ṣe ni wọn tun ji ẹni ti wọn ran pe ko lọọ gbe owo atawọn ohun tawon ọdaran naa beere fun nibi ti wọn wa gbe sa lọ, ti wọn si n beere pe ki wọn tun mu owo itusilẹ miiran wa ko too di pe awọn ju onitọhun naa silẹ.

ALAROYE gbọ pe Ọjọruu, Wesidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2023 yii, ni wọn ran oniṣẹ kan pe ko lọọ gbe miliọnu kan Naira ati ọpọlọpọ ounjẹ tawọn ọdaran naa beere pe awọn fẹẹ gba fun wọn lati doola ẹmi iyawo pasitọ to wa lahaamọ wọn silẹ.

Ohun to jẹ iyalẹnu ninu ọrọ ọhun ni pe ẹni ti wọn ran lọ sọdọ awọn ajinigbe ọhun pe ko lọọ ko owo atawọn ẹru yooku ti wọn beere fun lawọn ọdaran ọhun tun ki mọlẹ, ti wọn so onitọhun mọlẹ, ti wọn ko si jẹ ko kuro lakaata wọn mọ. Wọn ni o digba ti wọn ba mu owo miiran wa kawọn too juwọ rẹ silẹ.

Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to lọ lọhun-un lawọn ajinigbe naa ya wọle Pasitọ Ajiboye to wa lagbegbe Elerinjare, lẹgbẹ ilu kan ti wọn n pe ni Idofian, nijọba ibilẹ Ifẹlodun, nipinlẹ Kwara. Lakooko ti wọn waa ji iyawo pasitọ ọhun gbe ni Ọlọrun  ko ọkan lara awọn ọmọ rẹ yọ, nitori pe ṣe ni wọn iba ji oun naa gbe pẹlu iya rẹ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, S.P Okasanmi loun ko ti i le fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ  lakooko tawọn oniroyin pe e lori foonu rẹ.

Leave a Reply